Chigbo re o |
Gege bi AWIKONKO se gbo, Chigbo, eni
odun marundinlogoji lowo palaba e segi ni ojule kejidinlogun Asikolaye Gasline,
Ijoko Ota, nigba ti won so pe enikan lo fi ejo e sun ni tesan olopaa to wa ni
Ota
AWIKONKO gbo pe Obinrin kan ti won pe
oruko e ni Peju, to je oludasile ajo kan to maa n daabo bo awon omode nilu
Abeokuta lo loo fe ejo Chigbo sun ko too di pe DPO Olopaa, Akinsola Ogunwale
lewaju awon olopaa lati loo fowo ofin mu.
Nigba to n soro, Arabinrin Peju Osoba
so pe okan lara awon osise oun lo loo se idanilekoo nile eko Bannis College
Ota, o ni leyin idanilekoo naa ni omokekere naa lo baa, to si salaye fun wipe
oko egbon oun maa n ba oun lasepo pelu agidi.
O lomo naa so pe se ni Chigbo maa n
hale mo oun pe ojo toun ba so sita loun maa ri aye mo, eyi lo si ko iberubojo
baa ti ko fi le soobu sita. Bakanna lo lomo naa n gbon lohun nigba to n soro
naa.
Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Abimbola
Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe lesekese ti Komisana awon ti gbo lo ti
pase pe ki won maa gbe bo ni Eleweran lati tesiwaju ninu iwadi.
Abimbola ni bo tile je pe Chigbo ti
jewo pe looto ni, to si so pe ise esi nii, o ni Komisana ti dari ejo naa lo si
eka olopaa to n ri soro fifi omo se owo eru lati tesiwaju ninu ejo naa.
Bakanna lo tun fi kun pe Chigbo ko ni
pe ti yoo fi foju bale ejo. O wa gbawon araalu lamoran lati maa bojuto awon omo
won daadaa.
No comments:
Post a Comment