Bawon kan se n so pe efun ni, bee lawon
kan n so pe eedi ni, sugbon ohun tawon mi in n so nipe ise aye ni, atipe boya o
ni awon tobinrin naa ti se, eyi to je ki won fi ejo e sun awon aye ti won fi
gba omo naa pa mo lowo.
Gege bi AWIKONKO se gbo lose to koja,
won ni lati ojo ketadinlogun osu yii, iyen ninu ose to lo lohun ni adugbo
Ifelodun, Onifade Itele, ijoba ibile Sango/Ota ni isele naa ti waye nigba ti
won ni Bisola fo igi mo omo e lori, tiyen si ku patapata.
Orisirisi aheso ati awuyewuye la gbo
lori ohun to fa isele naa nitori pe bawon kan se so pe Bisola ran Toheeb nise
lojo naa, sugbon won lomo naa ko tete de, igba to maa fi de, ko rii nkan to
ran, ibinu yi lo mu ki Bisola mu igi to wa larowo to e, to si fo mo o lori.
Bee lawon kan so pe ise ti Bisola ran
Toheeb lojo yen ti poju, eyi lo mu ko so pe oun ko le lo sibi kan mo, a fi koun
sinmi die, sugbon odi ni won ni Bisola gba oro e si, to si bere sii lu. Gbogbo
bi won se ni Bisola n lu Toheeb, lo n so pe a fi koun pa.
Se won ni aye ko ni gba omo pa mo wa
lowo, oro ko ri bee nigba ti won ni se ni Bisola mu igi nla kan to si bere sii
fi lu omo e, sugbon won ni ko mo igba to fi gbe igi naa soke, to fi la mo lori,
loju ese ni won ni ooyi ko omo naa, to si subu lule.
Ere ni won koko pe e, nigba to n pariwo
Toheeb dide. Won lo ba sare wole lati lo bu omi, sugbon nigba to fi maa pada
jade sita, omo naa ti wa eyin lu, elemi si ti gba nkan e.
“E gba mi” lariwo ti won lo o pa eyi to
mu kawon kan yoju sii pe ki lo sele, sugbon iyalenu lo je fun won nigba ti won
ri oku omo naa ati Bisola pelu aagun to n bo loju e boyoboyo.
AWIKONKO gbo pe awon kan ni won ni won
so fun un pe ko tete pe oko e, ko si salaye nnkan to sele fun un ki oro naa ma
baa le ju bi o ti ro o lo. Nigba to pe oko e to si so fun un, loju ese ni won
niyen fibinu so fun un pe ko lo je tabi ko mo bo se maa se e.
Yoruba maa n so pe ‘ki Olorun ma je ki
a mo saare omo atipe kOba oke ma je ka fi owo wag be omo wa sin’. Oro yi ko ba
Bisola nile nitori won ni nigba ti oju pafiri, ni lo na mu jiga ati ada to si
gbe ile ninu ogba ile ti won n gbe, nibe lo sin omo naa si.
Lesekese ni won ni Bisola gbe eru e, to
si sa kuro nile nitori itiju nla lo je fun un ladugbo. Sugbon awon araadugbo
naa to mo nkan to se lo lo foro naa to awon olopaa ekun Itele leti.
Won ni latigba naa ni DPO yen, Ogbeni
Lukmon Adejumo ti bere ise iwadi, to si yan awon otelemuye lati wa Bisola ri.
Ose to koja ni won ri Bisola lagbegbe Iyana-Ipaja ti won si mu.
Nigba to n jeri soro naa, Agbenuso
olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe looto nisele naa, atipe Komisana
won, Ahmed Iliyasu ti tare ejo naa sodo awon olopaa otelemuye, iyen SCIID lati
tubo sewadi.
Iliyasu nigba to n leri so pe a fi ki
Bisola foju bale ejo leyin iwadi ododo. Owa gba awon araalu lamoran pe ki won
ma se dekun lati maa foju awon odaran han sawon olopaa, ki won ma se maa se
idajo lowo ara won nitori pe ohun gbogbo lo nii se pelu ofin.
No comments:
Post a Comment