Ayinke lu omo-omo oko e kan lapa ni l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 23, 2017

Ayinke lu omo-omo oko e kan lapa ni l’Ogun

Lomo naa ba mu orin ope bonu
 
Titi di asiko ti a fi n ko iroyin lawon eeyan si n so pe asasi loro obinmrin kan ti won n pe ni Iya Adija ti won loo lu omo-omo e kan lapa ati ese lose to koja latari pe o seesi to sori eni to fi n kirun.

Foto eyin omo naa
Gege bi AWIKONKO se gbo, lagbegbe Canaan Land ni Matogun, ijoba ibile Sango-Ota nipinle Ogun loro naa ti sele nigba ti won so pe obinrin naa ti gbogbo ferese ati ilekun nigba to n da seria fun omo-omo e, omo odun merin, iyen Risikat Fayomi.

Ohun ti a gbo nipe, okan lara awon araadugbo to n koja lo lo gbo igbe omo naa lati oju ferese, nibe ni won leni naa ti fura pee kun ti omo naa n sun yato si ki won maa na lasan. Eyi lo mu ki okunrin naa ke gbajari sawon eeyan toku ladugbo lati lo gba omo naa sile.

Gbogbo bi won se n kan ilekun yara ni obinrin naa so pe ko si nnkan to kan won ninu oro ebi oun, ki won maa lo, sugbon won so pe gbogbo bi won se n gbiyanju lati fi ipa si ilekun naa wole lo ja si pabo, eyi lo mu won lo foro naa to awon olopaa Ajuwon leti.

Awon olopaa naa lo lo gba omo naa sile, sugbon nigba ti won ri ipo ti omo naa wa, lo mu won tete gbe e lo si Osibitu Tamara to wa ni Ajuwon, Akute fun itoju. Oro beyin yo nigba tawon dokita sayewoo omo naa, ti won si rii pea pa ati ese e ti kan sinu.

“Mo dupe mo fiyin f’Oluwa, won o tori mi r’aja lowo baba oniposi, mo dupe mo fiyin f’Oluwa”, eyi lorin ti won lomo naa nko fun bii ojo meta leyi to fi n dupe lowo Eleda e pe iya-iya e ko gba emi e laitojo.

Lara awon dokita to bawon akoroyin soro lori isele omo odun merin naa so pe, latigba ti won ti gbe omo naa de odo won lawon ti n toju e nitori pe won o ri enikan ko yoju pe omo awon ni, bee ni won sakiyesi pe Risikat kii jeun deedee, won lobinrin ti febi paa.

Gbogbo bi won se n so pe ki omo naa pada sile lo n so pe, ki won ma je koun ku bayii nitori pe ile naa dabi orun apaadi foun ni. O lojoojumo ni Ayinke maa n na oun.

Lara awon agbaagba ladugbo, Ogbeni Adewunmi Oyebode nigba to n soro so pe awon ti wa obinrin naa de tipe nitori pe Risikat kii se omo-omo e gan ni pato, o ni iyawo baba iya Risikat ni Ayinke, latigba ti won ti muu de odo e nigba to pe odun kan lo ti bere sii toju e lona aito.

Okunrin naa so pe nitori airikan-sekan ni baba e, Abass ti won ni oko tirela lo n wa fi ko omo naa sile fun iya e, eyi lo muu gbe lo sodo iyawo baba e lati maa toju e, ti won si ni ko boju wo eyin lati wa wo alaafia e.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi so pe kayeefi ni oro Ayinke si n je fawon araalu, paapaa awon olopaa, bo tile je pe se ni obinrin naa n so pe oun ko mo nnkankan nipa bi omo naa se kan lapa. O ni iwadi si n lo lowo lori e. Bee lo so pe obinrin naa yoo foju bale ejo nigba ti aje oro naa ba si mo lori.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI