Amosun foba tuntun je n’Ihunbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 27, 2017

Amosun foba tuntun je n’Ihunbo

Gomina ipinle Ogun, Asofin agba Ibikunle Amosun ti gbe opa ase fun Oba Joseph Olamide Adesiyan Inakankan gege bi Onihunbo tilu Ihunbo nijoba ibile Ipokia.
 
Gbagede ileewosan ijoba ibile to wa ni Ihunbo ni ayeye igbade ati opa ase naa ti wa nibi ti awon eeyan jankanjankan atawon araalu ti pejo lati ye Oba tuntun naa si.

Gomina Ibikunle Amosun
Amosun nigba to n gbe opa ase fun oba tuntun naa so pe oriire nla lo je fun awon araalu lati tun ri Oba tuntun ti won yan naa atipe eleekeji ti iru ayeye nla bayi maa waye niyi nilu Ihunbo.

Amosun ti Ogbeni Dolapo Adewunmi, eni to je oludari eka to n ri si eto ifinijoye ati ijoba ibile soju fun so pe inu oun dun fun suuru tawon araalu ni lakoko ti won fee yan Oba tuntun naa. O so pe eyi ko wopo lawon ilu kaakiri nitoripe ija ni won maa fi n yan oba tabi olori won.

O wa gbawon eeyan paapaa awon ti won jo du ipo naa lamoran lati fowosowopo pelu Oba Joseph Inakankan ki alaafia baa tubo le maa joba laarin ilu. O ni ife ati alaafia lo se pataki lawujo, ki won si ri daju pe iwa omoluabi ko kuro laarin won. Bakanna lo so pe isokan lo le mu idagbasoke wole saarin ilu, ki won si lo anfaani naa lati fi mu idagbasoke ba ilu Ihunbo.

Saaju akoko yi ni alaga ijoba ibile Ipokia, Onarebu Amos Senayon ti gba Oba tuntun naa lamoran pe ki rii daju pe o fi ara e jin lati sise takuntakun nipa bi itesiwaju ati idagbasoke yoo se wonu ilu wa, ki won si le je mudunmudun ijoba awaarawa.

Ninu oro ti e, Oba Joseph Inakankan dupe lowo ijoba ipinle Ogun fun akitiyan e nipa idagbasoke ipinle Ogun paapaa lori oro oye ati oba jije nipinle naa. O wa seleri pe oun yoo sa gbogbo agbara oun lati se awon eto ti yoo mu isokan, irepo ati idagbasoke baa won eeyan paapaa ilu Ihunbo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI