Amosun fehonu han sawon Kositoomu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 14, 2017

Amosun fehonu han sawon Kositoomu


Gomina Amosun
Bo tile je pe titi di bi a ti n ko iroyin yii lawon ajo eso asobode, Nigeria Custom Service si fi n so pe iro lawon eeyan n pa wipe awon lawon yinbon pa Saubana Onila ti won fesun kan pe o se fayawo iresi lati Abeokuta si Sagamu.

Sugbon Gomina ipinle Ogun, Asofin Agba Ibikunle Amosun ti so pe ki ijoba apapo gba oun lowo awon osise Kositoomu naa lori iwa buruku ti won n wu, nitori pe won fee ba ipinle Ogun je mo oun lori ni. Amosun so pe, bi e o ba gbagbe, osu to koja lawon eeyan naa si lo o ja awon soobu ni Sango ti won si ko eru awon oloja lo.

O so pe iwa tawon eeyan naa n hu lenu ojo meta yii ku die kaato, nitori kawon oga won nijoba apapo tete da won lowo ko lati ma se je ki ipinle Ogun tu mo oun lori, nitori pe alaafia awon araalu lo je oun logun.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago mesan aabo aaro Ojoru Wesde ni Saubana atawon merin kan gbera ninu oja Kuto pelu moto won ti won fi ko iresi si, ti won si dojuko ona Sagamu.

Bi won se de abule kan ti won n pe ni Sowo ni Kobape, ni won lawon Kositoomu da won duro, sugbon won ni won o duro. E yi ni won loo bi awon Kositoomu naa ninu ti won fi gbe moto lati fi le won.

AWIKONKO gbo pe nigba ti Saubana atawon eeyan e ko duro, lo mu kawon Kositoomu bere sii yinbon fun moto won, sugbon won ni taya moto Mazda 626 ti Saubana wa ni ibon ba, to si gbokiti lo bawon moto min in to wa loju ona, eyi ti won so pe moto Camry kan tawon eeyan meta wa ninu wa lara awon moto naa, tawon yen si farapa yanna-yanna.

Awon moto ti ko din ni marun ni won fori gba ara won lagbegbe Siun loju ona marose Abeokuta si Sagamu. Ohun taa gbo nip e, nibi ti Saubana ti n rababa ja kuro ninu moto e to gbokiti pelu ara to fi sese ni okan lara awon Kositoomu naa ti loo yinbon fun lese, sugbon igba ti won ni ko tete ku, lo ba mu ko yinbon fun lori.

 Lesekese ni won so pe Saubana degbere faye lai kigbe “oro o”, gege bi won ti maa n se ninu sinima agbelewo. Loju ese ni won lawon eso asobode naa tin a papa bora leyin ti won pa Saubana.

Lara awon to ba akoroyin wa soro leyin isele naa so pe, awon toro naa soju e lo sare loo lati mo nnkan to n sele, sugbon awon asobode naa ti salo pelu moto won ki won too de ibi isele naa.

Sola Josiah ninu oro e, so pe “Abule Sowo ni Kobape lawon asobode naa ti bere sii tele wa. Baagi raisi meedodogbon lo wa ninu moto kookan ti a n ko lo si Sagamu. Sugbon nigba ti a de abule Sowo la rii pea won Kositoomu ti n tele wa. Ao kobi ara si nitori pe egberun marun ni won maa n gba lori irin ajo kan ti a ba lo.

“Ki a to seju pe, won ti bere sii le wa. Emi ni won koko da duro. Won yinbon fun taya moto Saubana to si gbokiti wogbo. Nibi to ti n gbiyanju lati jade ninu moto naa pelu apa ibon to ba, ni okan lara won tun ti loo yinbon fun lori, to si ku lesekese. Won gba moto mi, won si gbe e lo si ofiisi won.”

AWIKONKO tun gbo pe, yato si Saubana to ku nibi isele naa, awon marun otooto ni won farapa yanna-yanna, eyi lo mu kawon araalu binu gbe oku Saubana sinu oko taisi lo si ofiisi won to wa ni Quarry, Abeokuta lati loo fehunu won han.

Okunrin kan naa, Demeji Balogun nigba toun naa n jeri soro naa so pe “Nigba ti moto Saubana mu ori wogbo leyin to gba moto Toyota Camry kan, awon meta ni won ku lesekese. Awon eeyan ni won gbe oku Saubana tawon asobode naa yinbon fun lo si ofiisi won to wa ni Quarry Road, Abeokuta, ti won sig be awon oku meta toku lo si motuari.”

Ki won too de be, won lawon soja, olopaa, sifu difensi atawon fijilante ti wa lenu geeti awon eso asobode naa, eyi ti ko faaye gba won lati wo inu ogba naa, ki won si se ife inu won.

Alaga garaaji ti won ni Saubana ti n fi moto e sise, iyen Omo Show nigba to n ba akoroyin wa soro lojobo Tosde so pe edun okan niku Saubana je fawon nitori pe eeyan jeje ni, ko seni ti ko le ba sere.

O ni iyawo e sese bimo ni atipe ojo Tosde naa lo fee se ojo mejo ayeye ikomojade omo e tuntun naa, ko too di pe awon eso asobode naa demi e legbodo ti won si so awon ebi e sinu ibanuje nla.

Alukoro eso asobode, Custom, Usman Abubakar nigba to n soro lori isele naa so pe iro lawon eeyan n pa wipe awon kositoomu ni won seku pa okan lara awon oni fayawo naa. O ni won o ti e yinbon Kankan rara.

O tesiwaju pe gbogbo awon osise won ni won n gba idanileko lore-koore lori ise won. Bee lo so pe awon olopaa ti n se iwadi lori isele naa. O ni leyin iwadii won, lawon yoo to so oro sita fawon akoroyin lekunrere.

Abimbola Oyeyemi nigba toun naa n soro so pe, looto lawon gbo nipa isele naa, sugbon awon ko tii le fidi e mule pe awon osise asobode lo pa eni ti won n so. o so pe o so pe iwadii si n lo lowo.

O lesekese ti Komisana, Ahemed Ilyasu ti gbo lo ti pase pe kawon olopaa Sagamu ati Abeokuta lo sibe lati lo petu sawon araalu ninu, koro naa ma si lo koja bawon ko se ro.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI