Won layederu baale ko je ki won gbadun ni Abule Dada - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, February 11, 2017

Won layederu baale ko je ki won gbadun ni Abule Dada

Oloye Saubana, Ojulowo Baale
Awon ara abule Dada ni Itesi Abere Olumide ti rawo ebe sijoba ipinle Ogun pe ki won gba awon lowo okunrin kan, Azeez Adeoye, eni ti won lo n pe ara ni Baale, ti ko so seni to fi je oye Baale naa.

AWIKONKO gbo pe o ti le ni odun mejo ti Azeez ti n pe ara e ni Baale abule, to si n dunkoko mo awon agbalagba labule naa pe oun yoo pa won ni, atipe ko seni to le ye oun lowo wo, toun ba pa won tan.

Won lokunrin naa tun bere sii ta awon ile onile ninu abule naa, pe oun loun leto sawon ile to wa nibe nitori ipo toun wa. Bee ni won so pe ko seni to fokunrin naa je Baale abule Dada nitori pe o ni ilana tawon fi maa n yan oloye labule naa.

Bakanna ni won so pe Azeez lo ledi apo po pelu awon egbe idagbasoke to wa labule naa pe oun lawon ebun toun fee fit a won lore ti won ba fi oun se Baale.

Ayederu Baale
Oluwo Itesi, Oloye J.B. odebiyi, eni aadorin odun nigba to n bakoroyin wa soro lose to koja so pe oun loun leto lati fe eeyan joye labule naa nitori ipo toun wa.

O so pe lakoko tawon fee yan Baale ninu osu keji odun to koja, Oba Gbadebo to je Alake lo fun awon lase leyin tawon mu eni tawon fe gege bi Baale lo si Aafin Ake. O so pe Oloye Saubana Alabi Ajibesin lawon mu lo sodo Alake, ti Kabiyesi si fun ni iwe eri lojo naa.

Oloye J.B. Odebiyi
Nigba to n bakoroyin wa soro lori aago, Oloye Azeez Adeoye so pe oun ni Alake fun ni iwe eri gege bi Baale ninu osu keji odun to koja pelu ifowosopo awon araalu ati egbe idagbasoke meji, iyen Akari ati Ifesowapo.


Okunrin naa so pe oun yoo ko awon iwe eri toun gba wa fun akoroyin wa, sugbon nigbati akoroyin wa ko ri Oloye Azeez lojo to seleri ni akoroyin wa pe wipe a n reti awon iwe eri naa, sugbon okunrin naa yi ohun pad ape oun ko setan lati ko awon iwe naa sile, atipe ejo naa ti de Aafin Ake.

Gbogbo iwe aridaju pe Oloye Saubana Alabi ni won fi je Baale ni Dada Itesi Atere ni a ri gba, to si wa lakata wa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI