Lara awon ileri tegbe oselu APC
se lasiko ipolongo idibo lodun 2014 sodun 2015 se fawon araalu ni pe awon yoo
pese ounje ofe fawon omoleewe kaakiri orileede Naijira, eyi si ti mu inu opo
awon obi atawon alagbato dun wipe wahala owo ounje ileewe ti won n fawon omo
won lojoojumo yoo dinku lorun won.
Bo tile je pe ise ko tii bere ni
pereu lori e, sugbon lara awon to gbegba ope lasiko naa lawon to n ta ounje
fawon omoleewe nileewe kaakiri nitori won gbagbo pe awon naa yoo nipin ninu owo
tijoba maa gbe sile lati fi pese ounje fawon omo naa.
Gomina Ibikunle Amosun |
Nipinle Ogun, ni nnkan bi ose
meta seyin ti Gomina Ibikunle Amosun so pe ijoba oun ti setan lati mu ileri naa
se nipa ipese ounje fawon omoleewe kaakiri lawon olounje nileewe to to egberun
meji nipinle naa ti n se ajoyo pe oriire nla lo de bawon.
Bo tile je pe opo awon ileri
tijoba APC se lakoko idibo ni won ko tii muse, eyi lo faa to fi je pe nigba
tijoba ipinle Ogun so pe awon fee bere eto ounje ofe naa, won ko fi gbogbo ara
gbaa.
Sugbon gbara tijoba ranse si won
pe won fee bawon sepade lori eto ounje ofe naa, ni inu awon kan ti n dun pe
awon ti bo saye.
AWIKONKO gbo pe, se loro naa yi
pada nigba tijoba ipinle Ogun so pe awon ti gbe ise ise ounje naa fawon oloselu
ti won mo nipa bi won ti n se ounje lati le din wahala ku.
Won ni ijoba so pe kawon to ti n
ta ounje tele, ti won ba si nife si, ki won maa ba ise won lo lawon ileewe ti
won wa, wi pe awon ko di won lowo. Eyi lo mu kawon eeyan naa bere sii ni ikun
sinu si ijoba ipinle Ogun lori igbese ti won gbe ti ko te won lorun.
Lara awon to bakoroyin wa soro
leyin ipade naa so pe igbese ti ijoba gbe naa ku die kaa to nitori pe ko ye ki
ijoba gba wakati ati akoko lowo awon nigba ti won mo pe awon ko ni pin ise naa
sodo awon.
Arabinrin Taiwo Onagbide so pe
“Nigba ti won pew a pe won fee ba wa sepade, won so pe ki a wa si Ake. Nigba ti
a de be ni won so pe awon ko nii le gbe ise naa fun wa nitori pe awon ti gbe
fawon oloselu ara won nitori pe awon ko fee gbe ise naa fun eeyan lasan.
“Opo ibi ni won ti pe wa lati wa
lo sepade, ti a n na owo apo wa lati fi wo moto, bee ni won tun n gba akoko
lowo wa, nitori a gbagbo pe won maa je kawa naa nipin ninu ise naa.”
Nigba toun naa n soro,
Oludamoran lori oro ise akanse nipinle Ogun, Arabinrin Tinuola Shopeju so pe
“Ileewe lo din die ni egberun meji (1,554) lo wa nipinle Ogun, sugbon a fee
bere pelu awon ipele akoko, iyen ileewe 874 la fee bere pelu, ko too di pe o
kari awon toku. Nitori pe a fee pari gbogbo igbese naa patapata.
“Lati le bojuto gbogbo awon
ileewe yi daadaa, ati gbe ise naa fawon osise leka ise ijoba pelu awon ajo
ipade obi ati oluko lati maa saboju to e.”
No comments:
Post a Comment