Afaimo
kawon eranko buburu ti won lo ti n pa awon nnkan osin je ladugbo kan ti won n
pe ni Ijamido nijoba ibile Ado Odo Ota ipinle Ogun ma bere sii pa awon eeyan je
bayii.
Gege bi AWIKONKO se gbo, won lawon
eranko buburu naa bi won Se n pa awon eran osin je bee naa ni won n se awon
eeyan lese.
Adugbo naa |
Oun taa tun gbo nipe lati nnkan bi odun
kan seyin lawon eranko buburu naa ti n yo won lenu, ti kii fi won lokan bale.
Inu awon Igbo nla kan ti won lo wa
ladugbo naa ni won lawon eranko naa yi n jade, ale ni won so pe won maa n jade
sita lati sise won.
Won leni to ba wa nita lakoko naa, se
lawon eranko buburu yii ma n le won lati pa je.
AWIKONKO tun gbo pe opo igba ni won
ti ko leta sijoba ipinle Ogun nipase ijoba ibile Ado Odo Ota lati wa ba won wa
nnkan se si wahala ti won n koju.
Won ni alo leta lawon n ri, won kii
ri abo e. Bee ni won ni alaga ijoba ibile naa ti fi won lokan bale lori wahala
naa sugbon oro enu lasan ni won lo n so fawon.
Bakanna ni won so pe se lawon eranko
naa ma n bu ramuramu bi kiniun. Won lawon ile ti igbo naa wa niwaju ita won kii
le jade ti aago meje ale ba ti lu toripe igba naa lawon eranko yii maa n jade
sita.
Samuel Oyedele to je okan lara awon
to n gbe nitosi igbo naa nigba to n ba akoroyin wa soro nirole ojo Eti Friade
so pe ose meji seyin lawon mu leta lo si Oke Mosan lati le tun ran won leti, o
ni awon ko tii gbo nnkankan lati odo ijoba titi di asiko yii.
Okunrin naa tun so pe lojobo Tosde ni
awon eranko naa tun pa agbo meta loru mojumo Fraide. O wa so pe kijoba tete gbo
ti won, kawon le ni alaafia ati ifokanbale ladugbo naa.
Enìkan lara awon araadugbo to so pe
ka foruko noun lasiri nigba to n bakoroyin wa soro laaro ojo Abameta Satide so
pe awon kii le sun daadaa loru toripe se lawon eranko naa maa n kun, ti ariwo
won ko ni je ki won le sun.
O so pe awon igbimo kan ti ko leta
sijoba ipinle Ogun sugbon ti won o tii ri apadabo leta naa. O so pe kijoba tete
bawon wa nnkan se soro naa, kawon si le naa gbe igbe alaafia.
No comments:
Post a Comment