Oba Adedotun Aremu Gbadebo to je
Alake tile Egba, Okukenu kerin lo ti foju bale ejo giga kan to wa ni Isabo,
Abeokuta lojo Aje Monde to koja yii.
Bo tile je pe kayeefi lo si se
opo awon to gbo nipa e pe ki lo le fa ti ori ade ile Egba yoo se lo kawo poyin rojo
niwaju adajo ile ejo, sugbon oro naa ti wa foju han gbangba pe nitori oro oye
jije lo faa tawon oloye kanka merin laafin Ake fi gbe Oba Gbadebo lo sile ejo.
Awon oloye naa ni; Oloye Abayomi
Rotimi to je Oluwo Kemta, Oloye Ayinla Bankole to je Odofin Kemta, Oloye
Zaccheaus Alatise to je Sakotun Kemta ati Oloye Rilwan Oresanya to je Are Ombo
Kemta.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO
leti se so, ninu ejo tawon eeyan naa pe ni won ti so pe Oba Alake, Adedotun
Aremu Gbadebo yan Ogbeni Oluyinka Kufile gege bi Aro tilu Egba, ti ko si je kenikeni mo nipa bi won se yan okunrin
naa.
Won so pe Ogbeni Kufile ko ye
leni ti won le so pe o leto si oye nile Kemta, atipe eni tawon omo ilu Kemta ba
fowo si gege bi oloye ni yoo je, kii se pe Alake lo maa fa eeyan kale gege bi ife
okan e.
Awon eeyan naa war o adajo ile
ejo lati da Alake, Gomina ipinle Ogun ati Adajo agba lowo ko lati ma se yan
okunrin naa, iyen Oluyinka Kufile gege bi Aro
tilu Kemta digba ti won yoo fi yanju oro naa.
Agbejoro won, Ogbeni Abass M.A
tun so fun adajo naa pe, ona ti won gba yan Ogbeni Kufile gege bi Aro-Egba tako ofin to gbe oro oye jije
odun 1957 kale. O wa ni ki ile ejo da okunrin naa duro, ki o si yee farahan
tabi ki o maa se ojuse gege bi Aro-Egba.
Adajo naa, Onidajo Mobolaji Ojo
wa sun igbejo naa si ojo kejilelogun osu keta odun yii. O so pe ki iwadi tubo
tesiwaju lekunrere.
No comments:
Post a Comment