Won ni odaran paraku ni
Seun Egbegbe ati Ayomide Oyekan |
Oro naa ti koja oju tawon eeyan fi n woo bayii,
nitori pe afaimo ki okan lara awon gbajumo to n sagbateru ere ori itage, tiata
nni, Olajide Kazeem topo mo si Seun Egbegbe ma sewon lori esun ole jija ati
gbajue to n se kaakiri, eyi ti won fi kan an.
Bi e o ba gbagbe, ojo mefa pere lo ku ki Seun
Egbegbe foju bale ejo lori esun ti won fi kan lojo kejilelogun osu kokanla odun
to koja wipe o n gbiyanju lati ji foonu olowo nla mesan towo won to milionu
merin naira salo lagbegbe Computer Village, ikeja nilu Ekoo.
AWIKONKO gbo pe oro naa lo gbe dele ejo, bo tile je
pe milionu kan naira ni adajo to wa nidi ejo lojo naa so pe ki won fi gba beeli
e pelu oniduro meji ti won n san owo ori won deedee. Adajo naa, Arabinrin Y.O.
AjeAfunwa sun igbejo miran si ojo kejo osu yii, iyen osu keji odun 2017.
Iyalenu lo tun je nigba ti won tun mu okunrin naa nibi
to ti lo lo gbajue fawon awusa meji ti won n paaro owo dola si naira. Won loo
so fun won pe oga awon dokita loun ni osibitu kan to wa nitosi ibi ti won wa.
Gege bi AWIKONKO tun se gbo, lati odun 2015 ni won
so pe Seun Egbegbe ti n sise buruku naa, to n lu awon eeyan ni jibiti owo,
atawon ohun ini won, bo se n lu won ni jibiti l’Ekoo, bee lo n lu won ni gbajue
n’Ibadan, bakanna ni ko tun je ki won gbadun l’Ogun, gege bi AWIKONKO se gbo.
Seun nigba to ji foonu |
Nigba ti owo palaba e segi lodun to koja, opo awon
tokunrin naa ti lu ni jibiti ni won yoju, ti won si wa n tako o ni tesan awon
olopaa Area F l’Ekoo, sugbon oun taa gbo ni pe, awon kan ni baa bebe, ti won si
pa ina oro naa, nitori won ko fee koro naa ju bee lo.
Lojo ti asiri e tun tu l’Ojobo Tosde ose to koja
pelu enikeji, Ayomide Oyekan, tawon olopaa si gbee lo si tesan won, nibe lawon
eeyan tun ti bere sii yoju lati tu awon asiri ikoko e lorisirisi nipa iwa
odaran to hu seyin. Nibe ni won ti mo pe osu kejo odun 2015 ni won ti n wa a.
AWIKONKO gbo pe esun merindinlogoji ni won fi kan
Seun Egbegbe ati Ayomide Oyekan, igbakeji e nile ejo, eyi ti won loo lodi si
ofin orile ede Naijiria. Yato sawon ti won loo ti lu ni jibiti lorisiri ona, ko
din ni ogbon lawon ti won se pasipaaro owo to tun lu ni jibiti lati osu kejo
odun 2015 si osu keji odun yii, iyen 2017.
Lara awon to ti lu ni jibiti ni Mohammed Sanni,
milionu meji ataabo naira (N2.46m) lojo kinni osu kinni odun yi; Jubriala Ado,
milionu kan ati oodunrun naira din legberun meta (N1.257m) lojo kesan osu kesan
odun 2016; Hassan Amodu, egberun lona eedegberin naira (N600,000) ninu osu
kinni odun 2016; Sanni Hassan, milionu kan ataabo naira (1.43m) pelu milionu
meta din die owo Euro (2,750Euro) ninu osu kejo odun 2015; Saidi Abdullahi ni
700,000 lojo kejidinlogun osu kerin odun 2016.
Bakanna ni Atairu Abdullaahi, milionu kan naira
lojo ketalelogun osu karun odun 2016; Abdullahi Babadisa, N650,000 ninu osu
kinni odun 2016; Abdurawan Hassan, milionu kan ataabo lojo kinni osu kinni odun
2017; Suraju Garuba, N850,000 ninu osu kefa odun 2016; Abdullahi Mumini,
milionu meji naira (N2.15m) losu kesan odun 2016; Garuba Hassan, N700,000 lojo
kewa osu kinni odun 2016; Sanni Muhammed, milionu meji naira (N1.89m); Barawo
Abdullahi, milionu meji ataabo naira (N2.6m); Yahu Alidu, milionu meji naira (N1.75m);
Tairu Musa, milionu meji naira (N2m).
Egbegbe ni ti asiri e tu |
Bee naa ni Muhammed Bello, oodunrun dola ($300);
Muhammed Usman, egberun lona eedegbeta naira (N450,500); Suleiman Shehu,
N1.276m; Nairu Musa milionu kan naira (N1.007m); Sanni Muhammed milionu kan
ataabo naira (N1.6m) ati egberun meta dola ($3,000).
Awon miran tun ni Umaru Haruna, milionu meji naira
din ni egberun lona oodunrun naira (N1.7m); Abubakar Musa, egberun merin dola
($4,000); Abdulrasaq Sanni, N1.7m; Abdullahi Babatunde, milionu meta naira (N2,77m)
ati bee bee lo.
Agbejoro olopaa, Ogbeni Effiong Asuquo nigba to n
soro niwaju Onidajo A.O Gbadamosi so pee sun ti won fi kan won lodi si ofin
kejo labala iwe odaran odun 2006, to si ni ijiya labe ofin.
Bo tile je pe gbogbo esun merindinlogbon ti won ka
si Seun Egbegbe ati Ayomide leti ni won
so pe awon ko jebi e pelu alaye. sugbonOgbeni Innocent Anyigor so pe ki adajo
naa ma se fi oju aanu wo awon mejeeji lati le je ki won gba beeli won, nitori
pe o seese ki won tun lo lu jibiti nibo miran ti won ba fi won sile.
Innocent ro ileejo naa pe ki won pase pe kawon
odaran mejeeji naa si wa lakata awon ki o si mu ojo ti igbejo miran yoo waye.
Naigba toun naa n soro, Onidajo Gbadamosi so fun
Agbejoro Oguntoyinbo wipe oun n gbero lati pase pe ki won gba beeli won tele
ni, sugbon, ko seese mo nitori pe o seese ki won tun lo daran nibo miran.
O wa sun ojo igbejo miran si ojo kerinlelogun osu
keta odun yii, iyen 2017.
Nile ejo lojo naa, opo lo n soro labele pe ki won
ju okunrin naa sewon lesekese nitori pe o ti pa opo awon eeyan lekun. Bee ni AWIKONKO
tun gbo lati enu awon araalu to soro nipa Seun Egbegbe wipe oogun isiju ni Seun
n se, lati le maa fi lu jibiti. Won so pe ibi to ti n ri owo ti e niyen.
No comments:
Post a Comment