Lojo
Aiku Sannde ose to koja lowo olopaa ipinle Ogun te awon afurasi odaran merin
lori esun idigunjale lagbegbe Oke-Ira, Agbara nijoba ibile Ado-Odo Ota ipinle
Ogun.
Gege
bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni se lawon eeyan naa lo ja okunrin
kan, Akeem Lateef lole egberun lona oodurun (#300,000) naira nileese e to ti n
yo bulooku lagbegbe naa ni nnkan bi aago kan aabo osan ojo naa.
Awon
merin naa ni Muse Ibrahim, eni odun metalelogun; Alashe Olaleye, eni odun metalelogun; Efe Ejoh, eni odun
merindinlogbon ati Olamilekan Adebayo.
AWIKONKO
gbo pe, bawon eeyan se de adugbo naa ni won ti bere sii yinbon soke lati fi
sise ibi won, ti won si bere sii fi ada, aake atawon eroja oloro min in ti won
ko dani hale mo awon araadugbo naa.
Bi
won se de odo Akeem Lateef to nileese bulooku naa ni won beere pe owo owo e da,
tokunrin naa si so pe ko si owo kankan lowo oun. Okan ninu won lo da igbaju fun
un pe ko gbe owo owo e fawon, ko too di pe o gbee le.
Ohun
taa gbo ni pe, Akeem sese lo gba owo naa lati fi san gbese awon to je lowo, ko
si fi eyi toku sise sori igba fawon onibara e, ko too di pe awon adigunjale naa
de lati wag baa lowo e.
Lara
awon araadugbo toro naa soju e ni won ni won te awon olopaa laago pe awon
adigunjale tun ti n sise won, ki won tete wa koju won. Loju ese ni won lawon
olopaa ti gbera lati lo kapa won.
AWIKONKO
gbo pe, bawon odaran naa se gbo pe awon olopaa ti de ni won ti koju ibon si won
lati bawon jijakadi. Sugbon nigba ti won rii pe owo won ko ka awon olopaa lo mu
ki won fee na papa bora.
Nibe
ni won ti mu awon merin towo te naa bale, tawon toku si juba ehoro.
Alukoro
olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi gege bo se so, o so pe nigba ti won foro naa
to DPO Agbara, Ogbeni Yemi Oyeniyi leti lo ti ko awon olopaa leyin lati lo doju
ija ko won.
Abimbo
so pe nibi ijakadi naa lowo ti te awon merin naa, tawon yooku won si na papa
bora pelu owo ti won gba lowo okunrin naa, sugbon awon nigbagbo pe laipe laijina,
owo olopaa yoo te won.
O so pe awon nnkan oloro
ti won ri gba lowo won ni aake, apo saka ti won ko obe si, fila iboju meta ati
igbo.
Agbenuso naa wa fi kun
oro e pe, Ahmed Iliyasu ti pase fawon olopaa FSARS pe ki won tesiwaju ninu
iwadii lati rii pe won rowo to awon toku ti won salo, lati le fi iya ofin je
won.
No comments:
Post a Comment