Ori ko Banji yo lowo awon ayederu babalawo n'Ijebu Igbo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 23, 2017

Ori ko Banji yo lowo awon ayederu babalawo n'Ijebu Igbo

Bi kii ba se ope Olorun to fi awon iko FSARS eka tipinle Ogun se sababi ire fun arakunrin kan ti won pe Anoba Banji latilu Ibadan ni, boya ki ba ti dero orun nibayii.

Awon ayederu babalawo
Ohun taa gbo ni pe se lawon kan pe okunrin naa lori ero ibanisoro e pe ko wa pade awon ni Ijebu Igbo, tokunrin naa ko si besu begba to te oko leti lo bawon latilu Ibadan to n gbe.

AWIKONKO gbo pe ori ero ayelujara ti won fi n bani dore, iyen Eskimi ni won ti pade Ogbeni Anoba Banji ti won si fun ni ero ibanisoro kan pe ko pe e.

Banji la gbo pe o beere pe ki lo sele toun fi maa pe e, teni naa si so pe ko dakun pe ero ibanisoro. Ninu aanu ni Banji fi pe e.

Banji nigba to n ba akoroyin wa soro nileese olopaa ipinle Ogun to wa ni Eleweran Abeokuta lose to koja so pe "Mo n sise lori ero ayelujara Eskimi lojo naa ti mo si ri pe enikan fe je okan lara awon ore mi, lesekese ni mo gbaa wole gege bi ore mi.

"Loju ese leni naa so pe ki n pe nomba kan to fi ranse si mi ti mo si beere pe ki lo sele ti maa fi pe nomba na. Se lo so fun mu pe ki n ti e si pee naa. O tun be mi lojo naa.

"Nigba ti mo pe nomba naa, ni won so pe ki n wa pade awon nIjebu Ignibo, mi o mo n kan to sele mo lojo naa. Mo ranti pe mo lo mu aso mi ti mo si teko leti lo bawon.

"Inu igbo kan ti wom mu mi lo lawon FSARS ti de, lesekese ni oju mi la ti mo si salaye fun won. Ko too di pe won ko won.

"Nibe ni won ti so fawon FSARS pe ise babalawo lawon n se atipe awon ni won ma n ba mi sise ki soosi mi le tesiwaju. Emi to je pe agidi nu mi fi n gbadura ni maa wa da soosi sile.

"Egba mi o. Mi o ni soosi kankan o. Fun aridaju, maa fun yin ni adiresi ibi ti mi n gbe lati wa topinpin boya looto ni mo ni soosi."

Awon ore meji naa nigba ti won so tenu won so  pe "Iro patapata ni okunrin naa n pa. O n wa ejo lati fi gbe ara e ni, ki o baa le tako wa.

"Looto lo je pe ori Eskimi lati pade e, aburo wa ti o maa n na wa wa onibara lo pade e to si so fun pe ki o ran oun lowo lati le je ki soosi oun tete dagba.

"Nitoripe aburo wa yen kawe, o si mo bi won se n lo ero auelujara daadaa lo je ki maa ba wa sise. Ise babalawo la fi n jeun. Ko si le da lawa naa n ba kiri.

"O ya wa lenu nigba ti okunrin yi so pe oun ko mo wa ri. To si je pe iranlowo li ba wa sodo wa."

Alukoro olopaa nipinle Ogun, Ogbeni Abimbola Oyeyemi nigba to n gbenu Komisana ipinle Ogun soro so pe eri aridaju ti wa wipe iro lawon odaran mejeeji naa n pa. Atipe oniruuru ise bayii lawon ti ba pade tawon si mo ete tawon odaran naa maa n lo.


Bakanna lo so pe ise iwadi awon olopaa ko tii pari lori oro naa latu tun le tan imole sii faye ri. O wa gba eeyan to n lo ero ayelujara paapaa nipa ti ibanidore bii Facebook ati Twitter lamoran pe ku won maa sora nipa awon ore ti won n ba pade lori ero naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI