Odunlade Adekola |
Gbajumo osere tiata nni, to je ambasado fun ileese
ikansiraeni GLO ati oti Goldberg, iyen Odunlade Adekola ti so pe kawon eeyan,
paapaa awon ololufee oun wa ba oun ya foto lojo ayajo ololufee, eyi ti yoo waye
ni ojo Isegun Tusde, ose to m bo.
Gege bi AWIKONKO se gbo, won ni ileese ti won
ti n ya foto ti gbajumo osere tiata naa sese si sagbegbe Agbeloba nilu
Abeokuta, lo ti ni kawon eeyan wa ya foto, ki won si gbadun ara won.
Oruko ileese naa ni Clean Image Studio, atipe kii
se ofe lawon eeyan yoo ya foto lojo naa, won maa san owo ni, o kan je pe iye to
fee gba lowo won maa yato si eyi to n gba tele gege bi ohun taa gbo.
Bakanna lokunrin naa tun so fawon eeyan pe oun ko
gba owo iwole lowo eni to ba wa, bi ko se pe ki won wa ya foto ti won yoo maa
ri wo titilai.
Odunlade Adekola gege bi eni to gbe si akoroyin wa
leti so pe, anfaani tawon to ba wa lojo naa yoo ri je ni pe oun yoo ba won ya
foto papo.
No comments:
Post a Comment