O MA SE O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 10, 2017

O MA SE O

Odaju abiyamo gbimo pa omo e

Adura ki a ma mo saare omo lawon obi to mo pataki omo maa n gba lojoojumo, nitori pe kii se n kan to dara ki obi foju ri ibi ti omo tobi ninu maa sun dojo ale. Sugbon ti obi ba lowo si iku omo e, kini ka ti pee?

Ko seni to le so boya asasi ni tabi eedi ni lori bi obinrin kan ti won pe oruko e ni Akintunde se dimo pe pelu awon kan lati lu omo e,  Rilwanu Akintunde, eni odun mokandinlogun pa lose to koja.

Gege bi AWIKONKO se gbo, lojo Aiku Sande to lo lohun ladugbo Oriola nilu Ibafo ipinle Ogun nisele naa ti waye nigba ti won so pe obinrin naa fesun kan omo e, Rilwanu pe o ji oun lowo gbe.

Egberun lona aadorun (90,000) naira ni won lobinrin naa so pe Rilwanu jigbe, tomo naa si so pe oun ko mo nipa owo ti iya oun n wa. Gbogbo bi won se n beere owo yi lowo Rilwanu ni won so pe o loun ko loun gbe e.

AWIKONKO gbo pe se lobinrin naa yari kanle pe Rilwanu lo gbe owo naa, eyi lo mu ko ranse pe awon godogodo meji, Kayode to je aburo e, ati Titus ti won so pe olopaa ni lati fiya je e nitori ko baa le jewo, sugbon won lomo naa n so pe oun ko loun gbe owo, oun ko mo nnkankan nipa owo naa.

Won ni nigba omo naa ko tete jewo ni won ba loo ti i mo inu yara kan ti won ti fin ibon taju-taju tia gaasi (tear-gass) si, sibe won lomo naa n so pe ki won lo tese ile bo oro naa, ki won fi nnkan ti won ba ri fi wa owo naa.

Riliwanu
Inu yara naa ni won ni Rilwanu wa fun wakati mefa gbako, ko too dipe oro naa ti fee yiwo, sugbon nigba ti won rii pe Rilwanu ti ku ni won bas are gbee lo si Osibitu Richland to wa ni Arepo boya won le du emi e, nibe ni won ti rii pe omi ti teyin wo igbin lenu.

Won ni bawon eeyan naa se rii pe Rilwanu ti ku ni won ti lo sin in si ori ile iya e to wa lagbegbe naa lati se oro naa ni oku oru, sugbon lesekese niroyin ti kan kaariki pe won ti pa Rilwanu.

Ohun ti a gbo nipe, lojo keji ti Rilwanu ti dagbere faye nipa esun ti ko mo nipa, ni obinrin naa sadede ri owo naa nibi to fi pamo si, eyi lo bi awon ore e atawon araadugbo ninu pe obinrin naa mon-on-mo pa Rilwanu ni.

Lojo naa ni won se iwode lati fehunu won han sisele naa, ti won si ya lo si ile Kayode to je aburo iya Rilwanu. Won si gbogbo awon ayalegbe ni won le jade ti won sib a awon dukia Kayode je.

Lojo naa ni won lo foro naa to awon olopaa Ibafo leti ti won sig be iya Rilwanu. Won lesekese ti Kayode ati Titus ti won so pe olopaa ni ti na papa bora, won fese fee.

Alukoro Olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe looto nisele naa ati pe awon ti mu iya obinrin naa, sugbon o so pe ise esu ni.

Abimbola so pe bo tile je pe awon meji toku ti na papa bora, tawon si n wa won, sibe awon ko tii ri aridaju to fi han pe olopaa ni Titus.

Bee lo so pe, Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa nipinle Ogun ti pase pe ki won gbe ejo naa lo si eka olopaa otelemuye lati tesiwaju iwadii won, sugbon laipe awon yoo ri awon meji toku naa mu nibi ti won salo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI