Idunnu subu lu ayo lose to koja lago
awon ajo eso alaabo ojulalakanfinsori, iyen Fijilante eyi ti Ogbeni Olusoji
Ganzallo je oga agba fun nigba ti ijoba ipinle Ogun labe Gomina Ibikunle Amosun
so pe awon nikan lawon fun ni onte lori oro aabo nipinle Ogun.
Soji Ganzallo |
Lori ariyanjiyan to ti n waye laarin
ajo Fijilante mejeeji, iyen Vigilante Service of Ogun state, VSO ati Vigilante
Group of Nigeria, VGN, ijoba ipinle Ogun so pe VSO nikan lawon le fowo gbaya le
lori wipe won kun oju osuwon lati mu ki alaafia de ba ipinle naa nipa oro aabo
to peye.
Amosun ninu oro e so pe pelu
iranlowo ajo VSO nipinle Ogun, iwa odaran ti dinku lawon agbegbe ati igberiko,
paapaa alaafia ti de saarin ilu, eyi to fi okan awon araalu lokan bale pe akoko
ti to lati sun asundokan ki won si honrun.
Oga agba fun ajo VSO, Ogbeni Soji
Ganzallo nigba to n soro dupe lowo Gomina Amosun fi aduro ti e, ati ipa to n ko
nipa pipese awon ohun elo fawon eso alaabo kaakiri ipinle Ogun, eyi to mu ki
ise rorun ti won n se rorun fun won.
No comments:
Post a Comment