Lose to koja ni igbakeji gomina ipinle Ogun, Arabinrin
Yetunde Onanuga so pe oun ti yo owo kuro ninu ejo toun pe nile ejo lori ti
odomokunrin kan, Idris Yussuf to so pe o n ya aworan oun.
Gege bi AWIKONKO se gbo, ojo kerindinlogun osu to koja
ni igbakeji gomina naa fesun kan Idris pe o n ya aworan oun atawon moto to n
tele oun laaro kutu ojo kan, nigba toun n lo sibi ise.
Lesekese ni Arabinrin Yetunde Onanuga ti gbe Idris lo si
kootu pe ki ejo bere. Idris to je okan lara awon osise alaabo to n so ile kan
to dojuko ile ti igbakeji gomina naa n gbe ninu Ibara lo bebe lojo naa fun
idariji, sugbon ti Onidajo Olajide Ilo si fi oju aanu wo lojo naa pe ki won gba
beeli ni egberun lona ogorun lojo naa, to si sun igbejo miran si ojo keje osu
yii.
Sugbon nigba ti igbejo na yoo waye, Arabinrin Onanuga fi iwe
ranse si adajo naa pe ko da ejo naa nu nitori pe oun ti dariji Idris, ko je ko
maa lo layo ati alaafia.
Ninu leta ti won ni Arabinrin Onanuga ko si adajo lo ti so
pe, oun dariji Idris latari gbogbo iwe ebe tawon eeyan Idris fi ranse soun,
atipe won tun wa ba oun lati bebe fun Idris.
Nibe ni Olajide Ilo to je adajo ti so pe, oun ni nnkan toun
tun fee so mo nigba ti eni to gbe ejo wa, to tun je igbakeji gomina ipinle Ogun
ti so pe oun ko se ejo mo, fun idi eyi, ki Idris Yussuf maa lo layo ati
alaafia.
No comments:
Post a Comment