Iwa ko nii fi oniwa sile atipe ko si bi
a o ti se ebolo ti ko nii run Ogbe, eyi lo ni ibamu pelu odomokunrin kan,
Ibrahim Akinola tawpn olopaa fi sile laipe yii, to tun pada loo jale.
Gege bi AWIKONKO se gbo, lojo Isegun
Tusde ose to koja nileese opaa ipinle Ogun rowo to Ibrahim lagbegbe Orimerunmu
ni Mowe, ipinle Ogun.
Ibrahim odaran |
Ohun ti a gbo ni pe laaro ojo naa ni
won so Ibrahim atore e kan ti yen ti na papa bora lo digun ja Ojupeju Joseph
lole, ti won si gba owo to to egberun lona igba naira lowo e.
AWIKONKO gbo pe se ni Ibrahim sa
okunrin naa, iyen Joseph ni ada niwaju ori lakoko ti won jo n jijakadi, ti won
si gbe owo naa ati telifisan alara ogiri e salo.
Ariwo ti won so pe Joseph n pa pe won
ti fee pa oun lo ma kawon to wa nitosi ile e ji, ti won si ranse sawon olopaa.
Loju ese ni won so pe DPO ekun Mowe, Ogbeni Charles Ebhuoma lewaju awon olopaa
lati lo koju ija si won.
Bawon olopaa se de pelu oko won ni won
ni Ibrahim store ti n gbiyanju lati salo, sugbon ori talo Ibrahim pelu
telifisan to gbe dani nigba ti enikeji e na papa bora pelu owo ti won gba naa.
Agbenuso olopaa ipinle Ogun, Ogbeni
Abimbola Oyeyemi so pe loot ni atipe awon ri lara awon eroja oloro ti won ko
dani ati eru ti won ji gba lowo Joseph bo tile je pe enikeji e juba
ehoro.
Abimbola je ko di mimo fawon akoroyin
pe bo tile je pe ko tii pe ti won fi Ibrahim sile logba ewon lori esun
idigunjale ti won fi kan, eyi ti ile ejo ran an lo sewon, sibe ejo miran tun si
wa ni Kootu ti Ibrahim n je lowo nipa iwa idigunjale naa lo si da le lori.
Agbenuso naa wa fi kun oro e pe Ahmed
Iliyasu to je Komisana olopaa ti pase pe ki won gbe Ibrahim lo sodo awon olopaa
FSARS lati le tesiwaju ninu ise iwadi won, ki won si rii daju pe ore Ibrahim to
salo naa si ko si pampe won.
No comments:
Post a Comment