Foluke pa omo oojo to bi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 21, 2017

Foluke pa omo oojo to bi

Ko si bi eni to n woju Olorun fun omo bibi yoo ti gbo nipa isele yii ti ko nii kawo sori yo omi loju nitori pe nnkan to n fojoojumo paa lekun lenikan wo sunsun lo ju sodo.

Foluke to pa omo e
Lose to lo lohun lowo olopaa ipinle Ogun te Arabinrin kan, Foluke Owolewa, eni ogoji odun lori pe o seku pa omo e to sese bi, iyen omo oojo.

Gege bi AWIKONKO se gbo, laarokutu Ojoru Wesde ose to koja ni won lobinrin naa bimo, sugbon ki imole too wo, o ti seku pa omo naa, o si ti gbe e sonu. Ojule ketadinlogun adugbo Ilupeju ni Anishere Unity Estate, Sango Ota lo ti sele.

Awon kan ni won so pe won ri oku omo naa nibi tobinrin naa ju si, eyi ti won si so pe won ko ri oyun mo ninu Foluke, to si je ki won fura pe o seese ko je omo e ni.

Won lawon araadugbo naa lo lo so fun awon agbaagba ladugbo naa ko too di pe igbakeji alaga ijoba idagbasoke ibile lo lo soro naa fawon olopaa lati wa da si.

Nigba ti won ni won n beere oro lowo Foluke pe ki lo faa, won lo so pe ko sowo toun le fi toju omo naa dagba.

AWIKONKO tun gbo pe Foluke ti seru nnkan bayii ri, to je pe opelope awon araadugbo ti won doola emi omo naa ninu salanga to lo soo si.

Alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n jeri soro naa so pe looto ni atipe igbakeji alaga idagbasoke ijoba ibile agbegbe naa lo lo so fawon olopaa ko too di pe DPO Akinsola Ogunwale lewaju awon olopaa e lo mu Foluke.

Abimbola so pe obinrin naa jewo pe idi to fi huwa naa ni pe ko sowo toun fi le too, ati pe awon omo oun meji ti won wa nile, tipatipa loun fi toju won, oun si mo pe eru nla ni eleyii naa maa je foun loun se pa danu.

Komisanna olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe ki won gbe Foluke wa si oluulese awon olopaa ni Eleweran, ki Iwadii si tesiwaju.

O so pe iwa odaju lobinrin naa hu, o si gbodo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI