Gege bi a ti mo pe oni ojo kokanla osu keji odun 2017 ni ojo ibi okan lara awon gbajumo sorororo, FIBAN to filu Abeokuta se ibugbe,
Kolawole Adejojo tawon eeyan mo si Kasnaty to je okan lara awon omo Aare ana
fegbe sorosoro, FIBAN lorileede Naijiria, Yemi Sonde Jigan Akala ti pariwo sita
pe oun ko mo idi tawon eeyan fi n so oun kiri.
Orisirisi iroyin lo n lo kaakiri igboro pe okunrin
naa maa n tiju lori telifisan nigba to ba n seto ti won pe ni Ariya N Flow ni
OGTV lojoojo Isegun Tusde, bee ni won tun so pe okunrin naa n sa lati ka iroyin
lori redio.
Kasnaty soro yi nibi ayeye ojo ibi e to se fawon
ololufee e ni rampe nilu Abeokuta.
O so pe, oun ko ri tenikeni ro, jeje loun lo. Oun
ko mo risin tawon eeyan fi maa lo maa so isokuso kaakiri pe oun ko le se nkan,
nkan bayii loun le se.
Gege bo se ma n so pe ‘emi yato sawon imajensi rare
to n fagidi boobu’, o loun ni misan ninu ise pedepede ati sorosoro toun n se,
kii se gbogbo nnkan ti won ba pe oun si loun maa da si.
O ni toun ba n seto nileese Telifisan, toun ba n wo
ile, ipe awon to n pe sori eto loun n wo lati gbe, ki lo fee ti oun loju nigba
to je pe oun maa n se MC lode ariya ti won ba pe oun si.
Looto ni sa, nitori pe, ko si itiju feni to ba n se
MC lawon ode ariya kaakiri nitori pe Kasnaty ti se MC nile kaaro-o-jiire bee lo
tun ti lo se MC fun won nilu Abuja
Ni ti ayeye ojo ibi naa, o so pe oun dupe lowo
Olorun fun ti oore ofe to ri gba nitori pe kii se mimo o se oun loun fi wa ni
ipo toun wa lonii bo tile je pe oun ko tii yo, sibe ebi ko pa oun.
Bakanna lo wa lo anfaani naa lati dupe lowo oga to
ko nise, Jigan Akala fun ti aduro ti e lenu ise naa, to si tun dupe lowo iyawo
e, Oyindamola, fun amoran ojoojumo. Bee lo tun dupe lowo awon ololufe e fun bi
won ko se deyin leyin oun.
No comments:
Post a Comment