E gba wa lowo awon osise immigration o - Adeshina - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 7, 2017

E gba wa lowo awon osise immigration o - Adeshina

Aare fegbe Ohori lorileede Naijiria, Ogbeni Adeshina Alabi ti pariwo sita pe kijoba apapo gba awon lowo awon osise to n ri soro iwole-wode, iyen Immigration nitori pe omo orileede Naijiria lawon naa.
 
Ogbeni Adeshina soro yii lakoko to n ba oniroyin wa soro lose koja nilu Ilaro, nibi to ti n fi ehunu e han sawon osise naa pe iwa won ko te awon lorun.

Ohori lawon eya Yoruba to tedo si aarin meji orileede Naijiria ati Seme nitosi Yewa. Gege bi itan, Oyo ni won ti se wa.

Okunrin naa so pe ojoojumo lawon eeyan naa n dawon laamu nipa iwe irinna, sugbon tawon maa n so pe omo orileede Naijiria lawon je, atipe eya Yoruba lawon, awon ko nilo lati maa mu kaadi idanimo kiri.

O so pe bawon ko ba ti fi iwe irinna wole sorileede Naijiria han awon osise to n ri si wole-wode naa, owo ni won maa n gba lowo won ki won too le fi won lorun sile.

Ninu oro e, o so pe “Omo orileede Naijiria ni wa, nitori pe eya Yoruba la je. A n fe kijoba gba wa lowo awon osise to n ri si iwole-wode lorileede yii, iyen awon immigration nitori bi won se n fojoojumo beere awon nnkan ti ko ye lowo won. Ki ijoba apapo ati ijoba ipinle Ogun dide lati ran wa lowo.”

Siwaju akoko yii ni Aare naa ti gbosuba kare fun Gomina ipinle Ogun fun awon akanse ise to n se, paapaa sawon agbegbe nile Yewa.
 O so pe eni ti Olorun yan lati oke wa fawon omo ipinle Ogun ni Gomina Amosun nitori pe laarin odun mefa to de, ipinle Ogun ti yi pada si oju tawon eeyan fi n wo.

O wa ro awon omo Yewa lati tubo fowosowopo pelu ijoba Amosun ki o ba a le se aseyori awon ileri to se fawon omo ipinle Ogun, paapaa ile Yewa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI