Dani Dosky |
Okan lara awon irawo olorin takasufe to sese n dide bo
nipinle Ogun, bo tile je pe o sese bere orin ko tii ju odun marun lo, sibe, ko
seni to teti si orin e ti ko ni gbosuba kare fun un, iyen Ayobami Adewunmi
tawon ololufe e mo si Danny Dowski ti so pe ogbologb olorin nni, iyen Oloogbe
DaGrin lo maa n mu ori oun wu nigba toun ba n gbo orin e.
Danny Dowski lakoko to n ba oniroyin wa soro lose to koja nilu
Abeokuta so pe ipele keji loun wa nile eko girama lodun 2012, igba naa loun gbo
okan lara awon orin DaGrin to pe ni PonPonPon to si si oun niye lati so pe oun
naa fee gbe gba orin.
Odomokunrin eni odun metadinlogun naa so pe bo tile je pe oun
sese setan nileeko girama lodun to koja ni, anfaani nla lo tun je foun lati
dojuko ise orin naa ni kikun nitori itara toun ni ninu e.
O ni orin kiko ko di oun lowo lati ma se tesiwaju ninu iwe
oun toku nitori iwe kika dara pupo, ati pe beeyan ko ba kawe mo ise to ba yan
laayo, onitohun ko ni kuro loju kan soso.
Danny Dowski wa ro awon eeyan leka ise orin, iyen awon promota
paapaa awon ileese to n gbe awon orin jade, iyen Record Label lati fi oju aanu
wo oun, ki won si ran oun lowo lati gbe oun jade, koun baa le mu ayanmo oun
laye se.
Bakanna lo tun so pe oun ti gbiyanju lati se awo orin single
kan jade pelu ifowosowopo awon ore oun kan, tawon eeyan si n kan sara soun pe
ise loun se, atipe koun tubo tera mo.
Ninu oro e, o so pe "Inu mi a dun ti
n ba ri eni to le ran mi lowo lati gbe mi sita.
"Ti n ba wa nibi to dake je, tabi ti n ba laarin
awon ore mi, mo kan maa n ri pe orin yen kan n wa ni, lesekese ni maa mu bairo
ati iwe, ti maa fi ko sile ki n ma baa gbagbe.
"Igba miran wa to je pe ti m ba koja nibi ti won ti n korin, ilu
atawon eroja orin ti won n lu si yen, mo le loo lati fi se agbekale orin temi
naa.
"Mo ti wo ile igbohunsile leekan pelu awon ore mi, mo si ti se awo
orin kan jade, iyen single tawon eeyan si n kan sara si mi pe mo gbiyanju.
Nitori "Street Thought" ni mo pe lati fi so awon nnkan to n sele
laarin awon odo nigboro, iyen ni pe igboro gbona."
No comments:
Post a Comment