Owo olopaa ipinle Oyo ti te awon afurasi odomokunrin merin
kan ti won ko daruko won fipa ba omodebinrin eni odun mokanla sun nilu Ibadan.
Gege bi AWIKONKO se gbo agbegbe NNPC loro naa ti waye, ose
abufo (detergent) ni won lomo naa n ba iya kiri lati le maa fi ri owo jeun
latigba toun ati oko e ti ko ara won sile.
Ose naa ni won lomo naa kiri lojo tawon odo radarada
agunmaniye yi pe e pe awon fee ra ose. Ose aadota naira ni won ni won ra lowo
ti won si fun un ni eedegbeta naira pe ko fun awon ni seenji, sugbon omo naa
loun ko ni seenji, ki won ba oun gbe oja oun.
Okan ninu won lo so pe ko tele awon lati wa lo gba owo e,
sugbon nigba tomo naa rii pe won le gbe oun lo tabi ki won se oun nijamba, lo
ba so fun won pe oun ko le tele won.
Gbogbo bi won se ni won n ro o pe ko tele awon, lomo naa n
yari pe oun ko lo. Nigba ti won rii pe omo naa fee lagidi lo mu ki won woo lo
sinu ile akoku kan to wa nitosi ibi ti won wa, nibi ti won lawon meji kan naa
ti n duro de won.
AWIKONKO gbo pe Lesekese ni won ti bo pata e, ti won si ko ibasun
fun karakara. Gbogbo bi won se lomk naa n sunkun, erin ni won n rin.
Igba ti won setan ni won ti omo naa sita pe ko maa lo, ti won
si kilo fun un pe ko gbodo so fun enikeni, nitori bawon ba gbo pe o so, awon
yoo luu.
Ekun ni won lomo naa sun de odo iya e, to si so nnkan to
sele. "Moku mogbe modaran" lariwo tobinrin naa n pa ko too di pe awon
eeyan yoju si, to si so nnkan tomo e so fun un, fun won.
Nibe ni won ti lo lati lo koju ija sawon onise ibi naa, ti
won si ko gbogbo won lo sago olopaa.
Alukoro olopaa ipinle Oyo, Ogbeni
Adekunle Ajisebutu komisana olopaa, Samuel Adegbuyi ti pase pe ki
iwadii tesiwaju lori awon eeyan naa nitori pe iya omo naa lo wa so fawon
olopaa.
No comments:
Post a Comment