Asiri Tunde to fee ji okada gbe l’Owode Ijako tu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 10, 2017

Asiri Tunde to fee ji okada gbe l’Owode Ijako tu



Titi di asiko yi lawon olopaa ipinle Ogun si n tenu moo pe awon ko nii foju aanu wo awon ti won ba mu pe won lowo si iwa odaran nipinle Ogun lori bi iwa naa ko tii dinku.

Laipe yi ni owo olopaa ipinle Ogun labe komisana Ahmed Iliyasu te Abey Tunde, eni odun marundinlogbon lagbegbe Owode-Ijako nijoba ibile Ifo nibi to  ti ji okada kan gbe.

AWIKONKO, gege bi a se gbo, won so pe Tunde ati ore e, ni won da olokada kan duro pe ko gbe awon, sugbon nigba ti won de agbegbe Owode-Ijako ni won so pe ko duro, nigba to duro to n beere owo lowo won, ni won yo ibon sii pe k obo sile, ko si mu kokoro okada fawon.

Won ni okunrin oloada naa ti won pe oruko e ni Umani Ndidi so pe oun ko le fi okada oun sile fun won, ayafi ti won ba pa oun, loju ese ni won so pe Tunde ti yinbon fun lese to si subu pelu okada.

Pelu bi won se ni Umani subu sile lo si n bawon faa pe oun ko nii gba ki won gbe okada oun lo. Nibe ni won ni enikan to ri won nibi ti won ti n fa oro naa ti te awon olopaa Sango Ota laago lati foro naa to won leti.

Loju ese ni won ni DPO naa, Ogbeni Akinsola Ogunwale ti dide to si ko awon olopaa sinu oko lati tete lo koju awon eeyan naa.

Nigba ti won maa fi debi tisele naa waye, inu agbara eje ni won ti ba Umani, ti won si so pe Tunde ati ore e ti na papa bora. Awon to ri won nigba ti won salo ni won toka ibi ti won gba fawon olopaa, ko too di pe won le won mu.

AWIKONKO gbo pe, nibi ti won ti n salo ni won ti ri Tunde mu ti enikan toku e si juba ehoro. Lara awon olopaa ti won duro ti Umani ni won gbe e lo si jenera osibitu Ota lati doola emi e, nibi to ti n gba itoju.

Agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi so pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe kawon olopaa FSARS tesiwaju ninu iwadii won lati rii pe owo palaba enikan toku to salo naa segi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI