Asiri Lateef tu sawon olopaa lowo l’Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 10, 2017

Asiri Lateef tu sawon olopaa lowo l’Ogun

Bee ni won tun ri awon adigunjale marun un mu

Ko si ojumo kan ki ijoba ipinle Ogun ma so pe awon ko fee gbo nipa iwa odaran mo, eyi to mu kawon olopaa gba ise naa se lati gbogun ti iwa odaran, ki won si rii pe won fo ipinle Ogun mo ni tonitoni.

Awon odaran merin
Lose to koja ni ileese olopaa kede awon towo palaba won tun segi nibi ti won ti lo sise ibi won kaakiri ipinle Ogun, bo tile je pe awon kan na papa bora lakoko tawon olopaa lo koju won.

Lara awon towo te lawon merin kan ti won loo digun ja okunrin kan, Akeem Lateef, eni ti won so pe ise awon to n yo bulooku ikole lo n se, ti won si gba egberun lona oodunrun naira, iyen 300,000 lowo e.

Awon naa ni Muse Ibrahim, eni odun metalelogun, Alashe Olaleye, eni odun  metalelogun; Efe Ejoh, eni odun merindinlogbon ati Olamilekan Adebayo ti won lo sise buruku naa lagbegbe Oke-Ira, Agbara nijoba ibile Ado-Odo Ota ipinle Ogun.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ni nnkan bi aago kan aabo osan ojo Aiku Sande to lo lohun ni won lawon toro naa soju e ranse sawon olopaa Agbara lati foro naa to won leti pe awon adigunjale ti n sise won ladugbo naa.

Loju ese ni won lawon olopaa ti DPO Agbara, Ogbeni Yemi Oyeniyi lewaju won lo koju awon eeyan naa. Lakoko ijakadi ni won ti rowo to awon mereerin tawon toku si salo.

Awon eroja oloro bii Aake, obe lorisirisi, igbo ati aso iboju meta ni won ri gba lowo won.

Bakanna ni Abiodun Tunde to ji okada gbe lagbegbe Owode Ijako. AWIKONKO gbo pe okan lara awon toro naa soju e lo tawon olopaa lolobo pe Abey ati ore ti yinbon fun olokada kan ti won pe ni Umani Ndidi lese, ti won si fee ja okada e gba.

Lesekese lawon olopaa Sango Ota ti dide soro naa, ti DPO Akinsola Ogunwale si lewaju won, ko too di pe owo palaba Abey segi lakoko toun ati ore e ti n salo.

Siwaju sii lowo tun te Prosper Kerry l’Ogijo lakoko toun atawon ore e meji kan tawon ti na papa bora lo ja oteeli kan, Tulamania ladugbo Odo-nla lole.

Lara awon to wa ni oteeli lojo naa ni won so pe won te awon olopaa Ogijo laago pe ki won gba awon lowo awon adigunjale. Lakoko tawon olopaa de be lowo palaba Kerry segi nigba tawon meji toku juba ehoro.

Abimbola Oyeyemi so pe Komisana olopaa, Ahmed Iliyasu ti pase pe kawon Olopaa FSARS bere ise iwadii lati rii pe won rowo to awon toku.

Bakanna lo tun so pe Ahmed Iliyasu so pe kawon araalu tubo maa foju awon asebi han, ki ise aabo ilu le tubo kese jari, nigba to n so pe awon ko ni gbawon odaran laaye nipinle Ogun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI