Asiri Joseph to fipa bomodun meta lopo tu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 23, 2017

Asiri Joseph to fipa bomodun meta lopo tu

Erin keekee nibi ti Sundday Joseph to fipa bomodun meta lopo ladugbo kan niluu Ilaro ti n ka boroboro bii eye ayekooto nileese to n gbogun ti fifi omo sowo eru ati lilo omo nilokulo to wa nilu Abeokuta.

Ohun ti a gbo nipe Gege bi a se gbo, ladugbo kan ti won n pe ni abule Taju niluu Ilaro ni isele naa ti waye laipe yii.

Iwadii fi ye wa pe se ni won ni omo naa loo pon omi wa, nibi to ti n loo ni Baba agbalagba naa ti tan an wonu ile kan ti won ko tii ko pari, to si feyin omo naa le le,ko to wa ki kinni abe e si.

A tun gbo pe eje to n da labe omo naa lo muu koya e fura, ko to di pe o jewoo pe Baba Joseph lo fipa ba oun lo po,o ni o tan oun wonu ile ti won ko tii ko pari,bi eni to fee ran oun nise.

O ni gbogbo ariwo tomo naa n pa ko seni to gbo,nitori bo se fowo boo lenu,ti ti to fi te Ife inu e lorun,ekun ti won lomo naa n ke peluu eje abe e lo mu kiya e ke gbajare sita.

Loju ese ni won lo ti loo foro naa to awon olopaa leti, ti won si muu Sunday Joseph ti won lo si ti jewoo pe loooto loun ko ibasun fomo naa ati  pe bi ara oun se dide lojiji nibi toun wa lo je koun huwa naa.

Agbenuso awon olopaa nipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi nigba to n soro so pe botile je pe iwasdi si n lo lowo, ko dawon duro lati gbe okunrin naa lo sile ejo.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI