Ko si eni to wo ile Egba loni ri ipa igbese ijoba ipinle Oggun lori oro imototo, ko daa yoo ro pe awon angeli imototo sokale lati orun wa sile Egba ni.
Nibi ti oro naa gbe de duro bayii, ko tii seni to si le so igbeyin wahala tawon ara ile Egba ti bere sii ko si bayii lati igba ti gomina ipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun ti bere ise imototo ni pereu kaakiri ipinle naa.
Opo lo ti bere sii kabamo awon iwa aibikita won lori ainimototo to peye leyi to si le sokunfa ajakale aarun ati iku ojiji saarin ilu latari awon ile idoti ti won n gbe si awon oju opopona kaakiri.
Ko tii si agbegbe kan ni pato ti iru awon iwa ibaje yii ko tii jeyo. Beeyan ba wo ipinle Ogun tele paapaa ile Egba, yoo ro pe ko si ijoba nibe rara ni. Aarin meji awon opopona lawon araalu ma n gbe awon ile idoti lorisirisi si.
Awon adugbo ti awon iwa ibaje bayii poju si ni opopona oja Kuto, Omida, Lafenwa, Ita-Oshin, Osiele, Itoku titi de Odo-Oyo, Sapon, Abiola-Way titi de Aladesanmi, Adatan to fi de Enu-Gada, Ago-Oko, Car-Wash, Isale Igbein ati awon agbegbe mii in kaakiri ile Egba.
Okan lara awon to sun mo Gomina Ibikunle Amosun to ba akoroyin wa soro so pe awon egbe alatako ti won ko fee ilosiwaju fun ipinle Ogun ni won parapo lati maa hu awon iwa ibaje yii, ti won ko si fee ki ijoba to pada wa leekeji yii roju raaye se ijoba re botito ati botiye.
Sugbon awon kan dide tako oro naa, won ni ijoba ko pese awon nkan ati ibi idalenu si sawon agbegbe yii, to si je pe awon igbo tawon araalu n ribi da ile won si ni won ti fi ko ile, ile-epo ati ofiisi si, ko sibi tawon fee ma da ile won si lo mu kawon maa gbee si awon opopona fawon osise ijoba ti won n ko ile le maa bawon ko.
Awon kan ti won kii fe gboro abuku sijoba so pe ijoba pese nnkan ti won le maa da ile nu si fawon araalu, sugbon won ko loo, aarin meji opopona ni won n gbe idoti si leyi ti ko bojumu to.
AWIKONKO te siwaju lati sewadi eyi to n je okodoro, sugbon iwadi fi han pe agbegbe ti ijoba pese awon nkan idalenu si yii ko to nnkan pelu bi ile Egba ti se tobi to. Kuto nikan ni ijoba gbe ero idalesi si gege bi Afusa Agbaje to je okan lara awon onisowo suga se so ninu iforowero pelu akoroyin wa.
Ninu oro re "Ijoba ko pese awon ero idalesi iru eyi ti won gbe si oja Kuto sawon oja to ku, nibo nijoba fee ki a maa da ile e wa si."
Lori igbese ti ijoba ipinle Ogun ti bere sii gbe lati dawo ile gbigbe saarin meji opopona duro, opo awon onile ati oni soobu ni won ti bere sii pariwo sita pe ki Ijoba tete pese awon nnkan idale si sawon agbegbe kaakiri tori pe ko si ibi tawon fee da ile won si.
Sugbon ni bayii, angeli imototo ti sokale sipinle Ogun, paapaa, ile Egba. Ijoba ti so pe o to gee lori awon tawon araalu n gbe soju opoponaa kaakiri, O ni ko si aaye fun un mo.
Ojo abameta satide ojo keedogbon osu to koja yii to je ayajo ojo imototo kaakiri ipinle to wa lorile ede yi la gbo pe gomina Ibikunle Amosun jade pelu awon iko akoworin re, lati doju ija ko awon araalu ti won gbe ile sawon opoponaa.
Iwadi fi ye AWIKONKO pe aaye ose kan pere ni Ijoba fi se ikilo fawon araalu paapaa awon to n gbe ile saarin awon opopona kaakiri lati dekun iwa aibikita won siwaju igbese ti ijoba ti gbe yii.
Gomina ipinle Ogun, Seneto Ibikunle Amosun la gbo pe o bere ise imototo yii funra re lati Oke-Ilewo nilu Abeokuta ti i se ile Egba to si rowo to die lara awon to n hu iwa ibaje naa. Oun taa gbo ni pe, ni iwaju ile-epo World Oil ni Gomina ti rowo to awon odomokunrin meji ti won sese n gbe ile saarin opopo naa, ti o si ko won sinu okan lara awon oko akoworin to tele lati lo se idajo won. Egberun marun un naira ni a gbo pe enikookan won san gegebi owo itanran.
Opo awon ti Gomina Ibukunle Amosun rowo to lojo naa ni won gba idajo won lesekese. Bee lo tun ti opo awon soobu kaakiri ile Egba pa titi ise imototo fi pari lojo naa. Leyin naa ni ijoba ipinle Ogun wa paa lase pe kenikeni ma se gbe ile idoti sawon opopona tabi ki won da ile sinu kota mo.
Ijoba tun ti wa yan awon igbimo lori oro imototo lati maa mu awon to ba gbe ile idoti si opopona tabi ki won da ile sinu kota. Won ni eni ti owo ba te pe o tun gbe ile idoti si aarin opopona tabi ti won ba ri kota iwaju ita re to doti ju bo se ye lo, yoo fi enu fera bi abebe, ijoba maa ti ile tabi soobu naa pa ni, tabi ki eni naa san owo itaran sapo ijoba.
Nibi ti akoroyin wa ti n sise iwadi lo ti kan awon oni soobu meji kan ni agbegbe Modojutimi si Aladesanmi ti won n taku oro so pelu arabinrin kan to je okan lara awon to maa n gbe ile idoti sawon opopona. Oun ti a gbo ni pe, arabinrin naa n gbiyanju lati gbe ile saarin meji opopona to dojuko soobu won, eyi lo mu ki won pari wo lee lori pe ko gbe eru re lesekese, sugbon obinrin naa yari kanle pe kilo kan won ti oun ba gbe ile sibe, eyi lo mu ki won wo iya ija pelu re ti won si rii daju pe o gbe eru idoti naa lale ojo naa.
Ni bayii, awon araalu ti wa so ewe agbeje mo owo, won si tidekun awon iwa ibaje won yii. Gbogbo aarin meji opopona ati awon kota kaakiri ni o mo pafee bayii ti ko si si nkan to n je idoti nibe mo.
No comments:
Post a Comment