Ijogbon de bawon ajinigbe nipinle Eko
Gomina Ambode |
Ni bayii, wahala nla lo sokale sagodo awon ajinigbe ti won n
fojoojumo pale awon eeyan mo lati beere owo lowo awon ebi won, ki won too fi
won sile lori bi Gomina Ipinle Eko, Akinwunmi Ambode se towo bo iwe abadofin ti
ile igbimo asofin ipinle Eko fi sowo sii.
Gomina Ambode towo bo iwe abadofin yi lana Ojoru Wesde to
koja yi ewon gbere ni idajo eni ti won ba mu, ti won si fesun kan pe o lowo si
iwa ajinigbe nipinle Eko.
Abadofin naa ti wa di ofin bayii pe ajinigbe ti owo palabe
ba e ba ti segi, afi ko lo lo eyi to ku ninu ojo aye e logba ewon titi ti olojo
yoo fi de.
Nibe ni won tun ti so pe, bi emi kan ba jabo si lakoko ti
won ji eeyan gbe, won yoo yegi fun iru eni bee titi ti emi yoo fi bo lara e.
Gege bi AWIKONKO se gbo, awon omo ile igbimo asofin ipinle
Eko mu aba yi wa lati fi tako awon odaran to n fojoojumo ji awon araalu gbe, ti
won si n beere owo to le ni milionu naira lowo awon eeyan won ki won to fi won
sile.
Won so pe idagbasoke to de ba iwa ajinigbe gbe yi ti koja
afenuso nitori pe ko si ojumo kan kawon eeyan atilaawi yii ma sise ibi won, eyi
si n doju ti ijoba ipinle Eko.
AWIKONKO gbe abadofin yii jade lati fi din iwa odaran
ajinigbe yi ku nipinle naa. Won ni nibi ti eeyan ti won mu ba ti ku, idajo iku
ni won yoo da fun oru eni to ji eeyan gbe naa.
Gomina Ambode ti wa fi kun un pe, awon ti bere igbese ara
oto lati ri daju pe awon n daabo emi ati dukia awon araalu paapaa lawon ile eko
atawon ibi ti won tun le foju si nipa pipese aabo to peye fun won.
No comments:
Post a Comment