Oba
Halidu Lakoko to je Agura tiluu Agbagura niluu Abeokuta ti n jejo lori esun ti
Oluwo Adatan, iyen Oloye Mufutua Akinola pe pe kabiyesi ro oun loye gege bi
Oluwo eyi to so pe ko ba ofin ati ilana mu.
Gege bi
iroyin to te AWIKONKO leti se so, ile ejo Majisireeti keje to wa ni Isabo niluu
Abeokuta ni igbejo naa ti waye lose to koja nigba ti won so pe Adajo naa ti sun
igbejo naa siwaju di ojo kefa osu kerin odun yii.
AWIKONKO
gbo pe Adajo to n gbejo naa gege bo se so, o ni ojo naa loun yoo so boya igbejo
naa yoo tesiwaju tabi fagile esun ti won fi pe kan Oba naa ati Oloye Nirudeen
Olaleye ati Oloye Adenekan Jagunna.
Nitori
bi agbejoro awon ti Oluwo fesun kan naa se bebe pe ki adajo maa je ki igbejo
naa waye nitori ko lese nile.
Sugbon
ti Agbejoro Oluwo Adatan naa, Babatunde Fabunmi yari pe dandan ni ki igbejo naa
te siwaju labe ofin.
AWIKONKO
gbo pe Mufutau fesun kan Oba Agura pe ona ti won gba ro oun loye ko tona rara,
ati pe won ko ni eri gidi lati fi gbe e lese.
O ni se
ni Nurudeen Olaleye to ni kii somo ilu Ira, nibi toun ti joye, tawon Baba e kan
kole siluu naa ledi apo po mo awon kan, ti won ro oun loye. O ni lojo keji osu
keji odun 2014 lawon Ogboni Gbagura ati Ogboni Ojo foun joye naa, toun si gba
iwe eri e.
Sadeede
lo ni Nurudeen Olaleye bere si ni da ilu Ira ru leyin tawon fi je Balogun Ira,
o ni bo tile je pe kii somo ibe rara, Baba e kan kole sibe ni. O ni leyin toun
ri iwe pe won da oun duro, igbese akoko toun gbe ni lati ri Oba Agura tawon wa
labe e, toba naa si so pe oun ko mo nnkankan nipa e.
O ni
siyalenu loun gbo pe won yan elomin in, eyi ti ko dun mo gbogbo awon toun je
Oluwo le lori, idi niyii toun fi ro ile ejo lati gba oye oun pada, nitori o ni
se ni won fee fowo ola gba oun loju.
Bo tile
je pe awon tokurin naa fesun kan ko wa sile ejo, agbejoro lo kan yoju to si n
bebe pe ki won fagile ejo naa.
Amo sa,
awon omo Ilu Ira, ti Mufutau je Oluwo won ti fehonu won han lori iwa ti won ni
Oba Agura naa hu, ti won si ni a fi ko da pada sipo e.
AWIKONKO
ba Oloye Nurudeen Olaleye soro lori esun ti won fi kan oun ati Oba Agura,
Okunrin naa so pe oun ko le so nnkankan nitori oro naa ti wa nile ejo.
No comments:
Post a Comment