Lojoru
Wesde to koja yi nijoba ipinle Rivers so pe looto ni aisan iba LASSA miran tun ti jeyo
nipinle naa, eyi ti won so pe ise ti n lo lowo lati ma je ki aarin naa yika
ipinle naa, lori bo se je pe ileewosan aladani kan ni won ti sawari e.
Komisana
foro ilera nipinle naa, Ogbeni Theophilus Odagme nigba jeri soro naa so pe
kawon eeyan ma se foye lori aisan iba aseku pani naa nitori igbese ti n lo lati
da itankale aisan naa duro.
O so pe ara
alaisan kan ti won gbe wa sileewosan aladani kan ni won ti sawari aisan iba
naa, sugbon tawon akosemose dokita si ti n wa ona abayo sii, iyen ni pe lati
tele ilana ti ajo onilera agbaye, World Health Organization, WHO la kale lati
fi wo aisan naa, ti ko fi ni tan kaakiri.
Komisana
naa so pe awon ti n bawon ajo WHO soro lati rii daju awon molebi eni ti won
sawari aisan naa lara e ni won gbodo gba itoju to peye lati ma se je ki won tan
aisan iba naa kaakiri.
Odagme wa
ro awon araalu pe ki won maa je kawon to mo nipa oro ilera mo nigba ti won ba
sawari pe eni kan n po eje tabi won ri eje.
No comments:
Post a Comment