Lojobo Tosde
ana ni Gomina ipinle Bayelsa, Ogbeni Seriake Dickson kede Gomina ipinle Ekiti,
Ogbeni Ayodele Fayose gege bi alaga fegbe awon gomina to wa legbe oselu Peoples
Democratic Party, PDP.
Ilu Abuja
ni Gomina Dickson ti kede Gomina Fayose, eni to gba ipo naa lowo Gomina ipinle
Ondo, Dokita Olusegun Mimiko, toun naa gba ipo naa lowo Gomina ipinle Akwa Ibom
tele, Senato
Godswill
Akpabio.
Gege bi
AWIKONKO se gbo, ipinle marun ni won yan asoju won lo sibi ipade naa, ti won se
niluu Abuja. Inu ile Gomina Fayose to wa lagbegbe Asokoro niluu Abuja ni ipade
naa ti waye.
Lara awon
to wa nibi ipade naa ni; Alaga BOT, Senato Walid Jibrin, ati alaga alabojuto
gbogboogbo, Senato Ahmed Makarfi.
No comments:
Post a Comment