Unokyur, akekoo Babcock to pokunso, Won lo lowo aye ninu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

Unokyur, akekoo Babcock to pokunso, Won lo lowo aye ninu

A fi ki Olorun Oba oke maa daabo e bo wa, paapaa awon omo wa, ka ma ri asare ku ninu odun tuntun yii. Gbogbo obi ni mo gba a ladura pe won o ni fi oju sunkun omo lojo aye won pelu ogo Elédùmarè.

Unokyur
Titi di asiko ti a fi n koroyin yi ni iya ati awon ebi odomokunrin kan ti won pe ni Verishima Unokyur, eni odun mokandinlogun, to deede pokunso lati gba emi ara e lojo Aje Monde ose to koja si n je iyalenu lori igbese tomo naa gbe.

Agbegbe Sunkanmi Awoyingbo, Mafuluku Osodi lo ti sele. Ipele eko keji lo wa nileeko giga fasiti Babcock to wa ni Ilisan Remo nipinle Ogun, eka ikekoo imo nipa ise igbalode, Social Work lo wa.

Gege bi AWIKONKO se gbo, won lomo naa ti n so fun iya e pe oun ko ni pee ku nitori awon ami toun n ri loju ala ati loju aye, won lo lara n fu oun pe iku oun ti sunmo etile.

Ki oju ma ribi, Yoruba ni gbogbo ara loogun e, leyi to mu ki iya e mu lo sodo awon afadura jagun lati gbadura fun in. Bee la tun gbo pe orisirisi ile adura niya e tun ti muu lo fun adura lati ma baa toju sunkun omo.

Aburo e, Asor nigba to n soro so pe oun ko fura pe boya o n ipinu lati pokunso tabi pe o n wa ona lati gba emi ara e, bo tile je pe oun sakiyesi e pe ko sere bo se maa n sere. O loun beere pe ki lo sele, sugbon o so pe ko si nkan kan.

Asor so pe, koolu momi oun lo ji oun nibi toun sun si ni nnkan bi aago meje aaro ojo Wesde toro naa sele, o ni boun se dide lati lo silekun loun ri nibi to ti n mi jolonjolo bi aago elepon. O so pe awon meji naa niya awon bi.

Bakanna ni okan lara awon to sun mo won so pe latigba ti baba awon omo naa ti ku lodun meedogun seyin lobinrin naa ti n da gbe bukata awon mejeeji. O so pe looto lomo naa ti figba kan so fun mama e pe oun ri aami pe oun ko ni pee ku.

Okunrin naa so siwaju pe obinrin maa ti muu lo si orisirisi ile adura lati gbadura fun omo naa, sugbon iyalenu lo je pe nnkan mi in lo teyin e yo.

Bawon kan se n so pe asiko omo naa lo to ati wipe akosile ko le sai ma se, bee lawon kan n so pe kii se oju lasan, won lo lowo aye ninu ni. Sugbon nnkan to da wa loju ni pe oun gbogbo ye Olorun, gege bawon kan naa tun se so nibi isele lojo naa.

Siwaju akoko naa ni won ni Verishima ti fi ateranse ranse si okan lara awon ore e to feranmi ju fun ti odun tuntun ti a sese bo si yi, sugbon iyalenu lo je pe nisale ateranse naa lo ti koko pe "ka pade ni orun", eyi gan an lo n ya awon eeyan lenu pe ki lo le faa.

Okan lara awon oluko e nile eko girama nigba to n soro so pe, kii baayan se pe, jeje e lo maa n da lo. O so pe o soro lati mo nnkan nipa e, nitori pe kii soro.

Siwaju sii la tun gbo pe awon olopaa Mafoluku ni won wa ya foto isele naa lakoko ti won wa gbe Oju e lo si ile igboku si.

Lati le nnkan tawon eeyan tun so nipa e, paapaa awon to mo o daadaa, lo mu ki akoroyin wa lo wo o lori ero ayelujara ibanidore, Facebook, nibe ni a ti ri orisirisi nnkan tawon eeyan so nipa e.

Clifford Esuong so pe "Olorun mi, mo pada oro lati fi ibanuje okan mi han lori isele yi. Olorun mo idi e, ko si seni to le pe e lejo. Gerard Onyiuke so pe "Otosi omo kp reni foro lo. Iporuru okan lo ma n fa eyi. Gbogbo eeyan lo ro pe won okan ati eti toro ye. Sugbon ko seni to ye nigba ti a ba n rin lai wo Bata. Paapaa nigba to ba dabi enipe ko si isoro, to si je pe wahala wa."

Ifeoluwa Comfort so pe "Nigba ti mo gbo iroyin ibanuje naa, mi o mo bi ara mi se ri nitori gidi to mu mi fun ogun iseju gbako. Mi o gbagbo." Moses Mow naa pelu ibanuje okan so pe "Lesini kanna la jo lo. Omo daada ni nitori o ni suuru. O ti pe ti mo ti gburo e. Igba ti n ma gburo lo je pe iroyin iku e ni mo gbo." Browne Lawrence Deyley so pe "Inu yara e ni mo maa n sun saa ikekoo meji gbako. Se eleyi wa le je otito bi?"


Bi ogbeni Joshua Suleimanto je alukoro ileeko Babcock se so pe looto lo je akekoo awon, bee naa ni alukoro olopaa ipinle Ekoo Dolapo Badmus so pe nileewosan ti fi eri han pe looto lomo naa ti ku.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI