Primate Josiah Udofia |
Idunnu subu-lu-ayo
ninu ijo African Church lagbaye lori bi okan lara awon olori ijo naa lorileede
Naijiria se n se ayeye ojo ibi e pelu eka ijo naa ti won tun n si sipinle Akwa
Ibom loni Ojobo Tosde.
Gege bi AWIKONKO
se gbo, Alagba, His Eminence Primate Emmanuel Josiah Udofia ni won so pe, oni
Ojobo Tosde, ojo kerindinlogbon gan-gan ni ojo ibi e, ti won si n se lowolowo
bi a ti n ko iroyin yi nipinle Akwa-Ibom. Katidira (Cathedral) nla ni won so pe
Olorun lo o lati ko.
Bo tile je
pe, AWIKONKO ko tii mo ojo ori iranse Olorun naa, bee ni a o tii gbo nipa
agbegbe ti won ko ijo tuntun naa si nipinle naa, sugbon ohun ti a gbo ni pe,
iranse Olorun naa ti so pe oun ko le se ayeye ojo ibi todun yii lai je pe oun
pari soosi Katidira nla toun n ko lowo.
Lara awon
omo ijo African Church Solution Camp Ground nilu Abeokuta to gbe oro si
AWIKONKO leti so pe, Baba Udofia je okan lara awon agba iranse Olorun lorileede
Naijiria ti Olorun n lo lati yi itan aye awon eeyan pada si rere.
Bakanna la
gbo pe, Primate Udofia ko see fowo ro ti seyin nigba ti a ba n so nipa awon
iranse Olorun to n pase irorun ati alaafia saye awon eeyan nipa adura pelu
oruko Jesu Kristi.
Bee la tun
gbo pe awon Ojise Olorun ninu ijo naa lagbaye paapaa lorileede Naijiria, bii
Wooli Jeremiah Okunlola to je oludari eka ijo naa to wa ni Sam Ewang Abeokuta
lo lo silu Akwa Ibom lati lo ba Primate Udofia se ajoyo ayeye ojo ibi ati ijo
katidira naa ti won n si lowo.
No comments:
Post a Comment