Owo te Femi to lu soosi ni jibiti owo milionu meta ataabo naira Oro naa ti dele ejo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

Owo te Femi to lu soosi ni jibiti owo milionu meta ataabo naira Oro naa ti dele ejo

Ko si awijare kankan lenu Femi Dasaolu, eni odun metalelogoji ti won fesun kan pe o lu soosi kan ti won pe ni End Time Christ Ministry to wa nilu Abeokuta ni jibiti owo to to milionu meta ataabo naira, bi ko se awijebi.

AWIKONKO gbo pe osu kesan, odun 2014 ni Femi Dasaolu ti lu jibiti naa, to si n feni-doni, fola-dola titi to fi na papa bora latigba naa, ko too dipe owo te laipe yii ki won too gbe lo sile ejo Majisireeti to wa ni Isabo nilu Abeokuta lojoru Wesde ana.

Gege bi AWIKONKO tun se gbo, ile eeka marun lokunrin naa so pe oun fee ta fun soosi naa, eyi ti won so pe won fee fi ko soosi ti won yoo maa lo sibe, iyen permanent site sagbegbe Obada Oko loju ona Abeokuta siluu Ekoo.

Owo ile naa ni won lokunrin naa gba lowo won, sugbon ti ko mu won debi ti ile naa wa ko too di pe o salo mo won lowo. Adura ni won ni won fi gbe okunrin naa lada wa sile.

Oga olopaa, Ripeto Sunday Eigbejiale to gboro na lo siwaju adajo so pe odun 2014 ni won ti wa fejo okunrin naa sun, tawon si ti n wa latigba naa. O ni esun ti won fi kan Femi tako iwe esun odaran tipinle Ogun todun 2006.

Bo tile je pe Femi so pe oun ko jebi pelu alaye, sibe Adajo naa, Arabinrin Oriyomi Sofowora so pe ko si di alaye e mu di ojo ketalelogun osu yii ti igbejo miran yoo fi waye.


Bakanna ni Adajo naa so pe o seese ki won gba beeli Femi pelu egberun lona egberun lona igba o le aadota naira, #250,000naira.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI