Baba Ori-Oke |
Ijo naa, iyen The African Church
Solution Camp Ground to wa ni adugbo Sam Ewang, Leme nilu Abeokuta tii se
olu-ilu ipinle Ogun, ti Wooli Olatunji Jeremiah Okunlola topo mo si Baba
Ori-Oke ati Baba Ire-Owuro je alakoso e ni ijo ti a n soro nipa e.
Nibi ipago odun to koja |
Gege bi enikan to gbe oro naa si
AWIKONKO leti se so, ose kan gbako ni won fee fi se, ojo Aje Monde, ogunjo ninu
osu keta odun yi ni ayeye naa yoo bere ninu soosi naa, gbogbo eto ati ilana ni
awon igbimo ti won yan fun ayeye naa ti n se bayii.
Wooli Jeremiah Okunlola |
Ohun taa tun gbo nipe, won fee se
ayeye naa pelu ipago adura olodoodun ti won maa n se ni osu keta odun, iyen
Zion Congress, eyi tawon olorin emi kaakiri orileede Naijiria atawon iranse
Olorun ti Olorun n gba owo won sise iyanu lagbaye maa n wa nibe.
Bakanna ni AWIKONKO tun rii gbo pe
inu osu keta ni Wooli Jeremiah Okunlola maa n se ayeye ojo
ibi e, sugbon ko tii seni to le so boya Wooli naa maa see pelu eto ti won feese.
Bo tile je pe awon igbimo naa ko tii
pari ise lori awon igbese ti won n gbe nipa eto ayeye naa yoo se lo, sugbon ise
atunse soosi naa ti n lo lowo gege AWIKONKO se gbo.
Pepe tuntun Ijo naa |
Lara awon ojise Olorun to n bo lojo
naa ni Pasito Dayo Brown lati United Kingdom. Bee lawon olorin emi bii Funmi
Aragbaaye, Senwele Jesu, Tope Alabi, Ayan Jesu atawon min in naa o ni gbeyin
lati korin lojo naa.
No comments:
Post a Comment