Saka |
Gbajumo
osere tiata nni, to tun je aderinposonu lorileede Naijiria, Ogbeni Hafeez
Oyetoro topo awon eeyan mo si SAKA
ati Baba Kafaya ti so pe Olorun lo ko
oun yo lowo awon obinrin alagabagebe ti won fee koun maa bawon lajosepo lodun to
koja, iyen odun 2016.
Saka soro
yi nibi iforowanilenuwo kan to se pelu akoroyin laipe yi lori awon aseyori e
lodun 2016. Nibe lo ti so pe opo nnkan lo ye koun maa dupe lowo Olorun fun, fun
ti ogun toun la koja, paapaa, ni ti agbere sise.
Ninu oro e,
o so pe “Bi e ba je gbajumo, opo awon
obinrin ni won maa maa wa yin wa. Lopo igba ni won a maa seju sii yin lati le
je ki e ba won ni nnkan po. Opo won lo gbiyanju se simi lodun to koja lati le je
ki n bawon se nnkan ti mo ti pinup e mi o nii se mo ti n ba ti feyawo. Sugbon mo
dupe lowo Olorun to fun mi ni anfaani lati le gboju foo da.
“Iyawo mi rewa pupo, bee o tun si kere. Ki lo maa
je ki n wo ita. Paapaa julo, ko si ninu iwa mi pe ki n maa le obinrin kiri.”
Eni ti oro
e si n je kayeefi fawon ololufee nipa bo se n ko ise meji papo so pe, so pe bo
tile je pe oun si n sise oluko nile eko giga Adeniran Ogunsanya College of
Education to wa ni Ijanikin niluu Ekoo, sibe ko di oun lowo lati sise tiata
toun tun yan laayo, toun si feran e pupo.
O ni opo
awon to n gbe fiimu jade maa n fi aaye sile foun lati bawon kopa ninu fiimu
agbelewo. O so pe won maa n wo aago toun fi n sise gege bi oluko nile eko giga
ki won to pe oun lati wa sise.
No comments:
Post a Comment