Oro buruku toun terin nileejo kositomari (Customary Court)
kan to wa ni Igando lojoru Wesde ana, nibi ti Obinrin onisowo kan, Helen Otike,
eni odun marundinlaadota, 50 ti so fun adajo ileejo naa pe ki won tu igbeyawo
odun mejidinlogun ka.
Helen so
pe, o ti to odun mesan ti oko oun, Godwin Otike ti si oun laso wo, depo-depo ko
ba oun lajosepo. O ni se won mo pe kini naa ko see fi sara ku, nitori naa loun
se n bebe pe ki ileejo naa fi oju aanu woo un, ko sit u igbeyawo naa ka.
Hellen
nigba to n sunkun soro ni kootu lojo naa, so pe ni nnkan bi odun meje seyin
loko oun fi oun sile ninu ile adagbe oni yara marun, to si lo fe obinrin miran
silu Abuja. O ni se lawon n gbe gege bi ajoji ninu ile, ti ko sip e awon jo n
sebi loko laya.
O ni took
oun ba lo silu Abuja nibi to ti n sise, toun ba pe, eekookan lo maa n gbe foonu
e, to maa so foun pe oun (oko) a pe oun (iyawo) pada, sugbon toun ko ni ri
koolu e titi ti ile ojo naa maa fi su. O ni igba kan wa toun waa lo silu Abuja,
toun si sawari ibi to ti n sise, o ni oko oun ko je koun mo ibi to n gbe titi
di asiko toun n soro yii. O so pe leyin naa loun gbo pe oko oun ti fe iyawo
miran silu Abuja tiyen si ti bimo fun.
Hellen so
pe “Emi ni mo je ki oko mi mo egbon mi kan to n gbe l’Abuja nigba to de be.
Egbon mi lo si se atona e debi to ti n rise gba lowo awon eeyan kan. Sugbon se
lo gba awon eeyan naa ti egbon mi muu mo, to sis a kuro nile toun ati egbon mi
jo n gbe, kop e lawon olopaa wag be egbon mi nile.”
O tun so pe
oun sakiyesi pe oko oun ti feyawo, to si ti bimo meta ko to di pe o fe oun sile
gege bi aya, sugbon ko so nnkankan foun. O nigba toun ri aworan igbeyawo to se
pelu eni naa, lo too jewo foun pe, nigba toun si n dese loun se asise naa. O
loun dariji lojo naa, sugbon ko pe e lo loko oun tun lo fun obinrin kan loyun
ko too di pe o salo silu Abuja.
O war o
ileejo naa pe ko se oun laanu nitori pe oun ko tii bimo ri, oun si fee lomo
laye.
Oko e,
Godwin Otike nigba toun naa n soro so pe oun sa asala fun emi oun ni, nitori pe
iya oun lo so foun pe iya-iyawo oun lo wa nidi ijakule to de ba oun leyin toun
pade iyawo oun. O loun gba oro naa gbo nitori pe leyin toun fe obinrin naa ni
isoro de ba oun, toun si deni to fee le maa toro je.
Okurin naa
so pe, looto loun feran iyawo oun nitori pe obinrin daadaa to se e mu yangan
lawujo ni, sugbon oun gbe igbese naa nitori iwa ti iya e hu, lo je koun sa lati
daabo bo emi oun.
Adajo
ileejo naa, Ogbeni Adegboyega Omilola so pe oun sun igejo miran ojo
kejidinlogbon osu to m bo.
No comments:
Post a Comment