Wooli iranse Olorun nni, ti Olorun n lo lasiko yii, iyen Wooli Jeremiah Okunlola topo mo si Baba Ori Oke ti so pe ayeye odun mewaa ijo naa ti won fee se ninu osu keta odun yii yoo bere lojo kokanlelogun, iyen lojo Isegun Tusde.
Baba Ori Oke Solution |
Bo tile je pe ohun taa gbo tele ni pe, ojo Aje Monde, ogunjo
osu keta layeye naa bere, sugbon Baba Ori Oke so pe ko ri bee.
Wooli Okunlola je ko di mimo lakoko to n waasu lojo Aiku
Sande to koja yii, ninu soosi naa to wa ni Sam Ewang, Leme, Abeokuta.
Gege bi AWIKONKO se gbo, isoji olojo merin ni won maa fi
bere ayeye naa, eyi ti yoo pari lojo Eti Fraide, ti won a si se idupe lojo Aiku
Sannde to tele.
Bi eto ayeye naa too se lo niwonyi; Lojo Isegun Tusde ti won
yoo bere, laarin aago mefa si meje aaro ni ipade adura; aago merin aabo irole
si meje ni isoji ita gbangba. Bi won yoo si se see re fun ojo merin gbako.
Sugbon lojo Aiku Sannde ti won yoo kadi e pelu idupe aseyori
ayeye naa, orin ilu ati ijo ni won fee fi se idupe, bo tile je pe adura ti won
yoo gba lojo naa ko ju adura Ope lo, ni soki ni adura naa.
Lara awon olorin emi ti won n bo lati waa korin fun won lojo
naa ni Ajihinrere Funmi Aragbaye, Ajihinrere Tope Alabi, awon Ayan Jesu atawon
olorin emi miran.
Bakanna ni iranse Olorun Dayo Brown ko nii gbeyin lati fi
ijinle oro Olorun lati inu bibeli bo awon eeyan lakoko naa.
No comments:
Post a Comment