Gbajumo
osere tiata nni, to tun je apanilerin, Ogbeni Bolaji Amusan topo mo si Mista
Latin soro, ile kun lojo to ba AWIKONKO soro nipa Ajo Alaanu Mista Latin
Foundation to da sile lati maa fi ran awon araalu lowo. Bo tile je pe opo lo n
woye pe bawo ni okunrin naa se n see, ti ise tiata ko fi di ajo to da sile naa
lowo. Eyi lo mu ki AWIKONKO lo foro wa Mista Latin lenu wo. E iforowero naa bo
se lo.
Mista Latin |
AWIKONKO: Nje e le salaye fun wa idi ti e
fi da ajo alaanu Mista Latin Foundation sile.
MR LATIN: E se, Mr. Latin Foundation ni a
pe akole ajo alaanu naa, a wa fi sisale e pe “Gba emi kan la loni in”, emi la n
du, a kii se Olorun a si ki n se dokita, sugbon mo wo wi pe nigba ti mo kere,
mo jiya, baba mi o lowo, iya mi naa o lowo, awon to ni owo naa la n sare lo
baa.
Ninu
awon ta n sare lo ba yen, won n lawon ko le se fun wa, won le wa
danu,
ohun la fi wo pe, ti Olorun ba gbe awa naa ga ka huwa lati ran
awon eeyan
lowo, ka ma se bi awon ti o ran wa lowo, tori opolopo awon ti won o ran wa lowo
nigbayen ni won ko lowo mo loni in. Opolopo awon ti won si ran wa lowo ni gba
yen owo won o tori e parun. Bi o ran eeyan lowo ko ni kowo e ko tan, boo si ran
eeyan lowo ko ni ko tori e lowo ju Dangote lo.
Nigba ti
mo dagba ti mo n sise tiata awon eeyan ro pe mo ni owo lowo ni, ile mi, ofisi
mi, lokesan, Iranlowo ni won n ba wa, Awon min a ni, mi o rowo ile san, omo mi
wa nile iwosan, iyawo mi n saisan, iyawo mi fee bimo, melo lagbara mi ka lati
le da se, nigba ti mi o ki n se ijoba, ohun ni mo se wa roo wi pe e je ka da
ajo alaanu yi sile lati le san esan fun awon awujo to gbe wa de ibi ti a
de loni in, ka ran awon eeyan lowo niwonba ti agbara wa ba ka, eyi ti agbara wa
ko ba ka, aa pe awon eeyan ti won ni eje aanu lara lati ba wa saanu.
Opolopo
igba kii se owo la n gba lowo awon eeyan, elomin le nilo keke aro, a o wo
eeyan to lagbara niluu ka so fun won pe ki won joo, e fun wa ni keke aro
meji ka fun awon eeyan yi, won a fun wa, aa si dupe lowo won, ati beebee lo.
AWIKONKO: Odun wo gan le da ajo naa
sile?
MR LATIN: Odun 2011 la ti daa sile,
sugbon ise bere lori e lodun 2012, nitori nigba ta da sile a se iforuko
sile, leyin naa la koko wo ibi tawon eeyan yoo ti je anfaani ajo alaanu
yii, Ka sa so pe osu kewa odun naa nise bere ni pereu.
AWIKONKO: Ona wo lawon eeyan n gba lati
je anfaani ajo yii?
MR LATIN: Awon eeyan kooakan n ran
wa lowo, kii se owo ni won n fun wa, a le fe loo se ikede lori oro to se
koko , Iranlowo tawon eeyan n fun wa nigba min, elomin le fun wa ni moto pe ka
gbee lo fi se ipolongo, elomin le fun wa ni irinse ta maa lo, awon nnkan
tawon eeyan si n se fun wa lowo lowo niyen, sugbon nnkan tawa naa ni lapo ara
wa la koko n lo bayii, nigba tawon eeyan ba wa ri pe a n se iwon ta le se
ta, gbe dide, awon eleyinju aanu a le dide iranlowo si wa.
AWIKONKO: Bawo lawon araalu se tewogba
ajo yii?
MR LATIN: Nnkan ta wa n lo ni oruko ta a
ni to je pe Olorun lo fun wa ati awon araalu ti won tun ba wa gbe, iyen ni
idameji taa koko n lo bayii lati bawon eeyan wa soro, lati pe awon to danto min
wa. Lenu igba taa bere yii aimoye awon eeyan to n wa fun owo ileewe, ni Poli,
ni Yunifasiti, ni Koleeji, nileewe onipele keji, ati ileewe alakoobere ta n se fun
won lapo ara wa. Iwonba owo ta maa fi jeun la maa pin mo ara wa lowo, nigba to
je pe ki aye le da naa ni gbogbo wa jo n se, nitori naa bo je ogun naira lo ku
taa fe fi jeun teni kan si nilo idaji e, awa naa a fun, a n yi gbogbo e mo ara
won ni.
AWIKONKO: Se ipinle Ogun nikan ni abi
orile ede Naijiria ni ajo alaanu yii wa fun?
MR LATIN: Rara o. Kaakiri Naijiria ati
gbogbo agbaye lo wa fun, sugbon awon oloyinbo ma n so pe “Ile la ti n keso
rode”. Ninu ajo wa, a ti ni Hausa, a tun ni awon eeyan ti won mo ede Ibo so
daadaa, a ni awon omo Igbira lodo wa, ati beebee lo. A yipo gbogbo ijoba ibile
to wa nipinle Ogu, a ti lo si ipinle Oyo, ati beebee lo.
AWIKONKO: Awon wo lo wa ninu igbimo Mr.
Latin Foundation yi?
Baba Latin |
MR LATIN: Baba egbe wa ni Wasiu Ayinde
Marshal,, Alaaji Sefiu Alao je okan lara awon Baba Isale wa, Alaaji Wasiu Alabi
Pasuma naa baba isale ni, a tun ni awon eeyan loke okun. Nnkan ta fi ko awon
osere ati olorin jo ni pe yoo tun tawon eeyan ji pepe, Wasiu Ayinde Marshal
gege bi olorin, o ti gbe awon eeyan dide pupo ni ona e, ko to bere orin ni won
ti n pariwo pe orin soro ko o, sugbon nigba toun de, o so gbogbo e di
irorun fawon eeyan, o so orin di nnkan ti tomode tagba n ko nirorun, o je
awokose nidi ise orin. Wasiu Alabi Pasuma je eni to lawo sawon eeyan, bo
se n ko awon omode mora lo n ko awon agba mora, Sefiu Alao naa bakan naa
lori, iru awon ta n soro nipa e niyen lati tawon eeyan ji.
AWIKONKO: Bawo le se n koju mo ajo yi
pelu isetiata ti ko si ni di arawon lowo?
MR LATIN: Gbogbo e naa la n se papo ti
okan o le di ekeji lowo rara, ise ajo ta n se kii se ojoojumo, ise tiata kii se
ojoojumo, mi o le tori ajo alaanu yii ki n so pe mi o se tiata mo, ti mo ba se
bee, o tun mo si pe owo ajo ni mo fe maa na niyen, ise mi wa loto ti mo n se,
ajo
alaanu
je lati le ran awon eeyan lowo ni.
No comments:
Post a Comment