Ba asasi ni ka pe isele yii ni tabi
eedi, ko seni to le so nitori kayeefi lo je fawon to n gbe ni Owode Ijako nigba
ti won gbo pe odomokunrin kan eni odun metadinlogbon, Matthew Oguntade fun
iyawo e lorun pa nigba tiyen ko gba fun un lati ba sun.
Matthew Ogundele |
Iwadi fi ye wa pe o ti le ni nnkan bi
odun kan abo seyin ti Matthew ati Mary iyawo e ti fe ara won, ti Olorun si jogun
omo kan fun soso fun won ti won pe oruko e ni David.
Sugbon won ni awon mejeeji ko jo gbe
po gege bii koko laya, nitori pe won nile ti iya Matthew renti lomo e n gbe,
bee lomo naa ko nise kan pato lowo.
Oku Mary |
Iwadi tun fi ye wa pe soosi Kerubu
ati Serafu to wa ni Ajerogun, Odo Eran ka to de iyana Ilogbo ni Mary maa n lo
sun si latigba to ti pinnu pe o digba toko oun ba gbale koun to ba gbe po.
Ise awon to n dirun, hair dresser ni
Mary n se, amo nitori pe ise naa ko lo deede lo muu tun lo maa sise nileese
awon to n se ike jade.
Omo kan soso ti won bi |
AWIKONKO tun gbo ninu iwadi won pe
lojo Fraide tiselr naa waye, se ni Matthew pe iyawo e Mary lori aago pe mama
oun fi egberun kan naira sile fun in gege bi owo ounje, ko wa gba.
Owo naa ni Mary fee lo gba ti Matthew
so di nnkan mi in mo lowo, girigiri lo ko bo o mole to ni dandan, àyàfi ki oun
baa sun, sugbon ti Mary so pe ko si nnkan to jo.
Nibi ti Matthew ti fun un lorun pe
boya, o le juwo sile foun ni Mary ti dake mo on lowo to ku patapata.
Bi Matthew se rii pe oran nla loun da
yii lo muu ko ja awon oju ferese won, to si ju oku iyawo e yi seyin ile naa,
bee lo tun fi aso beedi iya e bo o, to wa gbe taya lee lori, to si salo.
Ni nnkan bi aago mewaa ale ti iya
Matthew de, to ba ile ti won dari, lo ti koko beere omo e yii, nigba ti ko rii,
lo sakiyesi pe won ti ja awon neeti ferese e yii, to si ri aso beedi e, bi won
lo se gba eyinkule e loo.
Aso to ri ti won fi nnkan mole lo muu
pariwo, tawon ara adugbo fi jade sita, nigba ti won yoo siju oku naa, lo di oku
iyawo omo e.
Oku Mary |
Gbogbo ale ojo tisele naa waye titi
di aaro ojo Aiku Sannde, ko seni to mo ibi ti Matthew salo àyàfi nnkan bi aago
mewaa aaro ojo Sande yii lowo awon olopaa to te Matthew ti won si muu loo si
tesan awon olopaa to wa ni Sango Ota.
Iwadi fi ye wa pe gbogbo igba to fi
salo, won lo loo gbe majele je ni, ami tiyen ko paa, gbogbo akitiyan lawon
olopaa n sa bayii lati rii pe ara e ya, ki won le ba sejo.
Ohun to tun wa da wahala sile bayii
ni owo ti won lawon olopaa gba lowo awon ara agbegbe naa iyen egberun lona
ogbon naira ko to di pe won gbe oku omo naa lo si mosuari.
Mary nigba to wa laye pelu omo e |
Won ni egberun lona merindinlogoji
naira ni won so pe won ni kawon koko loo mu wa, ninu e ni egberun mefa owo ti
won fi ya foto oku naa, ati egberun lona ogbon owo mosuari.
Bee ni won tun fesun kan awon olopaa
pe gbogbo awon tenanti ti won n gbe ninu ile tisele naa ti waye ni won so pe ki
won lo mu egberun mewaa naira ki won to gba beeli won.
Nigba to n soro nipa isele naa,
Agbenuso fawon olopaa, Ogbeni Abimbola Oyeyemi so pe looto nisele naa waye, bee
lawon si ti bere iwadi won.
Lori owo tawon ara agbegbe naa lawon
olopaa gba lowo won, o so pe oun ti bere lowo DPO agbegbe naa, iyen so pe iro
ni, ko si nnkan to jo.
Amo awon eeyan naa ni won awon si mo
awon to gbowo naa lowo awon.
Oku Mary tun re e |
No comments:
Post a Comment