Lori aisan iba LASSA to jeyo l'Ogun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

Lori aisan iba LASSA to jeyo l'Ogun

...Awon osise FMC si n beru

LASSA

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yi lokan awon osise osibitu ijoba apapo FMC to wa nilu Abeokuta ko tii bale,  ninu iberubojo ti aisan iba LASSA to seku la dokita kan, noosi meji ati osise ile igboku si kan losu kejila odun to koja ni won si wa bayii.

Bo tile je pe ko tii seni to le so pato bi aisan naa tun se pada wo ipinle Ogun leyin osu ti won so pe won ti bori aisan naa, sugbon awikonko gbo pe ko seni to tete fura pe aisan iba asekupani naa lo n se alaisan kan ti won ni agunbaniro ni, eyi ti won gbe wa fun itoju pajawiri, to si se bee gba emi e.

Ojo keta ti agunbaniro naa dagbere faye ni noosi ati dokita ti won n toju alaisan naa ta teru nipa, eyi gan an lo faa ti won fi lo wadi iku aitojo to lawon eeyan nileewosan kan to wa niluu Ibadan, iyen UCH.

Nibe ni won ti sakiyesi pe aisan iba LASSA lo seku lawon eeyan naa, ko pe si asiko naa ni okan lara awon osise ile igboku si nileewosan naa gbemi mi in, eyi ti iwadi si so pe iku naa ko seyin aisan iba buruku naa.

Sugbon latigba yii lawon osise atawon alaisan to wa losibitu naa ti n sise tifura-tifura lati ma baa lugbadi aisan naa. Bee lawon alaisan naa foju apa kan woye lati ma se ko aisan naa, kawon naa ma si ba ku iku ojiji.

AWIKONKO gbo pe lara awon alaisan kan ti pinu lati salo kuro losibitu naa, nigba ti won n bebe pe kawon noosi ati dokita yanda aeon lati maa lo sile, sugbon tawon yen n so fun won pe ki won ma beru, ko si nnkankan to maa se won.

Sugbon, latigba naa, ko tii si akosile pe enikeni tun lugbadi aisan naa, bo tile je pe iwadi bi aisan naa se pada wole sipinle Ogun si n lo lowo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI