Owo olopaa
ipinle Ogun ti te Latifa Lawal, eni odun mokandinlogbon ti won fesun kan pe o
da gbigbona le okan lara awon ti won jo n gbe, Olawale Amosun lori nilu
Abeokuta.
Gege bi
AWIKONKO se gbo, agbegbe Amolaso nitosi kootu ni Isabo, Abeokuta tii se olu-ilu
ipinle Ogun loro naa ti sele, ni gba ti won so pe Latifa da ewa to sese se tan
le Amosun lori, to sib o ara e ni torotoro, nitori oro ti ko to nkan ti won jo
n fa lojo naa.
Ni nnkan bi
aago meta aabo ale ojo Eti Fraide, ojo ketalelogun osu kejila odun to koja ni won
nisele naa waye, eyi to gbe obinrin naa de ago olopaa.
Esun meji
otooto to niise pelu apaayan ni won fi kan Latifa nigba ti won gbe e de kootu
Majisireeti to wa ni Isabo lojoru Wesde to koja yii. Nibe naa ni won ti so pee
sun naa tako ofin ninu iwe ofin ipinle Ogun todun 2006.
Bo tile je
pe Latifa so fun ileejo pe oun ko jebi pelu alaye, sugbon Adajo Olajide Ilo to
da ejo naa so pe ko gbe enu e sohun, to si foju aanu woo pe ki won si gba beeli
e, ki won to tesiwaju ninu ejo naa.
No comments:
Post a Comment