Kayeefi re o: Alaaganna bimo soju ona l'Arepo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 24, 2017

Kayeefi re o: Alaaganna bimo soju ona l'Arepo

Bi kii ba se opelope Olorun to gbe alaanu kan pade obinrin kan ti won pe ni Ubi Eze, eni ti won so pe alaaganna ni, bo ya ko ba ti gba ibi omo bibi dero orun alakeji

Gege bi AWIKONKO se gbo, ni idaji ojobo Tosde ose to lo lohun ni won lokunrin kan, Ogbeni Akinsanmi Akinlolu n joogi lati fi na ara e ladugbo Arepo nipinle Ogun, eyi ti won lo maa n se laraaro lo ti salabapade obinrin naa ninu agbara eje.

Eze ati omo e
Won lawon kan lo n seto lori bi obinrin naa yoo se ri omo naa bi, nigba to je pe ita gbangba ni ti ko si si ile nitosi. Ogbeni Akinlolu ni won loo seto lati gbe obinrin alaaganna naa lo si osibitu lati gba itoju leyin to ti bi omo naa, sugbon ti ko ni agbara mo.

AWIKONKO gbo pe, bi Akinlolu ti rii, lo ti sare lo si osibitu to sunmo agbegbe naa lati wa seto bi won yoo se gbe, bee ni won lawon kan naa tun loo wa oko ti yoo gbe. Ori aga kan to ni taya lese ni won so pe won fi gbe Eze de osibitu lojo naa.

Lara awon araadugbo naa nigba ti won n soro so pe, awon ti ri obinrin naa lojoru Wesde nigba to n paara adugbo naa, won lawon rii pe were to je ni ko je kawon kobi-ara sii pe o ti fee bimo.

Eze nigba to n bakoroyin soro ni osibitu naa, o so pe Majidun lagbegbe Ikorodu loun ti fese rin de Arepo. O ni oko oun lo le oun danu nitori pe ko le gbo bukata oun ati oyun toun ni fun, eyi lo si so pe o fa isoro to de ba oun latigba naa.

O lomo ipinle Delta loun, ko sit ii pe toun de ipinle Ekoo lodo ore oun kan toun n gbe, ko too dip e o le oun jade, bo tile je pe oun ko le so bi oyun naa se de ara oun. O so pe latigba ti ore oun ti le oun jade loun ti n wa ibi toun maa gbe, toun si n sun sibi ti ile bas u oun si, ko too dip e oun pade oko afesona oun, to si gba oun sile.

Ninu oro lo tun so siwaju pe “Leyin ti mo pade oko afesona mi ni mo pada lo si Warri lati lo ri awon obi mi. igba ti mo pada de ni mo too mo pe mo ti loyun. Oko afesona mi yi ko gbami laye lati wole nitori pe o ti kilo fun mi pe mi o gbodo lo.

“Latigba naa ni mo ti n gbe ni soosi Christ Healing Church to wa ni Majidun ko too dip e mo ba ara mi nibi yii. Mi o ranti boya mo okunrin kan ba mi sun, ko daa, oko afesona mi yii. Mo saa kan sakiyesi pe mi o ri nnka osu mi mo ki n too kuro ni Warri.”

Arabinrin Adesola Obey, to je oga agba fawon noosi ni osibitu naa, nigba to n soro so pr, awon ti ranse sijoba ipinle Ekoo lati maa se iranwo fawon to ba n tomo ikoko lowo, awon si bebe lati le seto bi Eze yoo se pada lo ri awon obi e. o ni won ti gba lati se iranlowo naa fawon.


Obinrin naa so pe bo tile je pe omo nikan lo si jade ninu Eze lakoko ti won gbee de odo won, o lawon lawon fun ni itoju , tawon si ko ibi (placenta) naa jade kuro ninu e. o so pe lesekese ti won ti gbee de lawon ti foro naa to awon olopaa atawon ajo aladanito n seranlowo fawon eeyan leti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI