Kashamu ati Fayose gbena woju ara won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, January 24, 2017

Kashamu ati Fayose gbena woju ara won


Fayose ko ye fun ipo naa –Kashamu
Gbenu e dake, nigbi tawon gomina ba ti n soro –Fayose

Oro m ba ro, ma ro ‘fo; efo m ba ro, ma ro ‘ko. Bee gele loro naa ri laarin awon agba oloselu meji nni, iyen Gomina ipinle Ekiti, Ogbeni Ayodele Fayose ati Senato Buruji Kashamu to soju ekun Ogun East nile igbimo asofin agba nilu Abuja nigba ti won gbena woju ara won.

Senato Kashamu
 Bo tile je pe omo egbe oselu kanna an ni won, iyen egbe oselu Peoples Democratic Party, PDP, sibe won ko fi ojuure wo ara won lakoko yii.

Gege bi AWIKONKO se gbo, ohun to da wahala sile laarin awon mejeeji ko ju ti alaga egbe awon gomina fegbe oselu PDP, eyi ti won sese fi Fayose se lojo eti Fraide ose to koja ninu ile Fayose to wa ni Asokoro nilu Abujai. Oro naa lo si n dun Kashamu pe ki lo je to je Fayose ni won mu.

Senato Buruji Kashamu ninu atejade to fita lojo Aiku Sannde to koja lo ti so pe Gomina Fayose ko ye leni to ye ki won fi se alaga fegbe gomina egbe oselu PDP nitori awon iwa itiju to so pe o n hu.

Kashamu ninu atejade so pe o je nkan ti ko bojumu gege bi egbe oselu alatako to n fee tun oruko e se lati le bo sipo pada lo maa wa yan eni ti ko to bii Fayose, ti eni tenu e n ja waya gege bi alaga egbe gomina fegbe naa.

Gomina Fayose
O so pe bi won se yan Fayose ko nii kan se pelu oun, sugbon gege bi okan lara awon omo egbe to si n fe ilosiwaju fegbe naa lo je koun so pe, eni to le mu ki alaafia ati isokan de sinu egbe naa lo ye ki won yan, kii se Fayose ti yoo da gbogbo eto egbe naa ru.

Nigba toun naa n soro nibi iforowero ti won se fun ileese telefisan Channels lale ojo Aiku Sannde, Gomina Fayose so pe ki Senato Kashamu gbe enu e dake nitori pe oro ti ko kan lo n da si.

O so pe Senato lasan lasan ni Kashamu, atipe o digba to ba di gomina ko too le maa da si oro, ko si maa se bi gomina.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI