Ogogo |
Gbajugbaja
osere tiata nni, Taiwo Hassan topo mo si Ogogo to tun je alaga igbimo to n dari
eto ayeye Onigba Aje to ma n waye nilu Ilaro lodoodun ti so pe ise tiata toun n
se lo je ki won fi oun se alaga igbimo Onigba Aje.
O
so pe leyin odun kokandinlogun ti won ti bere ayeye naa loun too darapo mo
igbimo lati maa gbaruku ti ayeye naa. O lodun 2012 ni won foun se alaga igbimo
naa.
Ogogo
soro naa nibi ayeye odun Oronna eleeketalelogun iru e to waye lojo Abameta
Satide to lo loun nilu Ilaro nigba to n bakoroyin wa soro.
O
ni bi won se foun se alaga igbimo naa lo ni ibamu pelu ise tiata toun n se,
atipe bi won se n ri oun ninu awon fiimu to niise pelu isese lo je ki won pa
enu po lati so pe koun wa se alaga won.
Okunrin
naa so pe ayeye Onigba Aje naa ko legbe ninu ayeye to n waye nile Adulawo,
Afrika nipa gbigbe Asa ilu tabi orileede laruge.
O
so pe Onigba Aje lo se pataki ju ninu awon eto ti won n la sile fun eto ayeye
odun Oronna olodoodun to ma n waye nilu naa toripe oun lawon n safihan e.
O
so pe "Onigba Aje nikan la n safihan fawon eeyan lati mo se ri. Ti a ba so
pe a safihan eegun, orisirisi odun eegun lawon eeyan n se. A ni Oja nla kan to
ti pe ti a n pe ni Igbo Aje, ti a ba fee lo lati lo sadura nibe la maa n gbe
nnkan ti a n pe ni Igba Aje dani, tori e la se n pe ni Onigba Aje."
Ogogo
nigba to n fehunu e han nipa iya to n je won ninu igbimo naa, o so pe owo apo
awon lawon fi n se gbogbo nnkan tawon n se lodoodun ki ayeye naa ba a le dun.
O
so pe ko seni tawon n gba owo lowo e yala lati odo ijoba ipinle Ogun tabi
igbimo to n dari ayeye odun Oronna.
Okunrin
naa je ko di mimo pe Onigba Aje nikan ni ohun ti won n safihan e, ti won si n
gbe laruge gege bi isese Ilu Ilaro ninu ayeye Oronna, sibe awon ko ri eto awon
gba fun igbelaruga Onigba Aje.
O
wa ro ijoba ipinle Ogun paapaa ijoba apapo pelu igbimo to n sakoso ayeye odun
Oronna lati foju aanu wo awon ninu igbimo naa, ki itesiwaju le tubo ba isese
Ilaro.
No comments:
Post a Comment