Bo tile je
pe gomina ipinle Ogun, Asofin agba Ibikunle Amosun ti so pe oun ko nii so
igbese tawon n gbe sita lori ti awon akekoo ti won ji gbe nitori aabo.
Ni bayii,
owo ti te awon afurasi meji kan ti won nigbagbo pea won ni igi leyin ogba fun
awon ajinigbe ti won ji awon akekoo atawon osise ileeko girama Turkish ti
orileede Naijiria, Nigerian Turkish International Colleges to wa lagbegbe
Isheri nipinle Ogun gbe lojo Eti Fraide ose to koja.
AWIKONKO
gbo pe, ilu Warri nipinle Delta lowo ti te awon eeyan meji naa lakoko ti iko
olopaa to so mo oga olopaa patapata lorileede yi, Abba Kyari lo ka won mo.
Philip
Kakadu ti inagije e n je Kakadu, eni
odun mokandinlogbon, eni ti won gba pe oun gan an ni olori won ati Romeo
Council ti won n pe ni Raw, eni ogoji
odun lawon meji naa ti won so pe asiri won tu sawon olopaa lowo. Won ni won si
n sayewo fawon ti won mu pelu won lojo naa.
Won so pe
ijoba ibile Bomadi ni Council, nigba ti won so pe ijoba ibile Warri North ni Kakadu
ti wa. Won so pe awon eeyan naa ti jewo pe awon lawon wa nidi ise naa.
Ipinle Ekoo
ni won ni Kakaku n gbe, se lo kan lo gbadun ara e ni Warri ni kowo palaba e too
segi pelu awon marun un min in towo te pelu e. Awon yen ni won so pe won n ka
boroboro fawon olopaa.
Bakanna ni
won so pe won jewo pe awon lawon ji Oba Iba niluu Ekoo gbe. Bee ni won ni awon
onile ti won jigbe lagbegbe Isheri ko seyin awon.
Bo tile je
pe gbogbo igbese lati ba Alukoro olopaa ipinle Delta, Ogbeni Donald Awunah soro
lo n ja si pabo lori bokunrin naa se ko lati gbe foonu e, sibe iwadii si n lo
lowo.
No comments:
Post a Comment