Lakoko ti won n pa ina |
Beeyan ba rin
sasiko ti ileepo kan ti won pe ni Rabeng to wa lagbegbe Adigbe nilu Abeokuta ti
jona, omi oju yoo jabo loju onitohun nigba tawon eeyan jona yanna-yanna nibi
ijamba ina naa.
Gege bi AWIKONKO
se gbo, ileepo naa wa ni adojuko gbajumo olounje kan ti won n pe ni Iya Sunday
l’Adigbe, ni nnkan bi aago kan aabo osan oni, Ojobo Tosde ni ijamba ina naa
bere.
Bo tile je
pe, titi bi a ti n ko iroyin ni a ko tii le so nnkan to fa ijamba ina naa,
sugbon awon eeyan dagbere faye nibi isele ijamba ina naa.
AWIKONKO
gbo pe, loju ese ti ina la nileepo Rabeng naa lawon eeyan to wa ladugbo naa ti
ranse pea won pana-pana atawon olopaa, bee ni won ranse sawon Sifu-difensi
atawon Fijilante lati wa daabobo emi ati dukia awon eeyan.
Won ni
kawon eso alaabo too de, awon eeyan ti gbemi min nibe, bo tile je pe, a ko tii
le so iye awon to ku nibi isele naa. Loju ese tawon Fijilante ti de ibi isele
naa, ni won ti bere sii fi omi pa ina naa.
Awon Fijilante lo n pa ina |
Bakanna la
gbo pe awon alaanu to wa lagbegbe naa ranse sileese pajawiri nileewosan ijoba
to wa ni Ijaye lati wag be oku awon tori tako nibi ijamba ina naa.
Ni bayii,
ohun taa gbo nip e, won ti gbe awon oku naa lo si ile igbokusi, iyen motuari to
wa ni osibitu ijoba to wa ni Ijaye, Abeokuta.
Lara awon to jona |
AWIKONKO
yoo te siwaju ninu ise iwadii lati mo nnkan to fa ijamba ina naa. Olorun a maa
so wa o. Amin.
No comments:
Post a Comment