Igbakeji gomina ipinle Ogun, Yetunde Onanuga fesun kan odomokunrin kan nilu Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

Igbakeji gomina ipinle Ogun, Yetunde Onanuga fesun kan odomokunrin kan nilu Abeokuta

Lojo Isegun Tusde to koja yi niroyin naa gba igboro ilu Abeokuta kan pe igbakeji Gomina ipinle Ogun, Arabinrin Yetunde Onanuga fesun kan odomokunrin kan, Idris Yusuf, eni odun metalelogun nitori awon yiya.

Gege bi AWIKONKO se gbo, iwaju ile ti igbakeji gomina n gbe ninu Housing Ibara nilu Abeokuta lodomokunrin naa ti n sise gege bi asogba, iyen sikioriti. Won so pe bi Obinrin igbakeji gomina naa se n jade kuro ninu ogba lati lo sibi ise e laaro ojo naa lomokunrin naa ki foonu e mole, to si bere sii ya awon oko to n tele jade.

Okan lara awon sikioriti Ibukun Oluwa to je ti oga agba tele fun ajo sifu-difensi (civil defense), iyen Ade Abolurin ni won pe Idris naa.

AWIKONKO gbo pe, bi oko kini in se jade, ti oko igbakeji gomina tele ni won so pe Obinrin naa ti ri Idris naa bo se n ya awon awon oko e bo se n jade. Won ni ironu obinrin naa ni pe, okan lara awon ti won n dode lati gba emi oun lodomokunrin naa je, pe bo ya won ran wa ni.

Won ni bo se taju kan to ri Idris naa, lo so pe kawon to n wa oko naa duro, to si ranse pe ki won lo gbe e wa foun, nibe ni won ni eru ti ba omo naa, ti ko si mo nnkan to le se mo.

Nibe lo ti beere pe ki lo de to n fi foonu ya oun, sugbon Idris so pe ara oun loun n fi foonu ya. Loju ese lo ti gbe Idris wole sinu moto e pe oun yoo pe lejo. Gbara ti won lomo naa gbo oro ileejo lo ti bere sii bebe fun aanu, sugbon won ni Arabinrin Yetunde ko gbo.

Kootu ni won lo ti so fun adajo to da ejo lojo naa pe ko da ejo fun Idris lori esun pe o n fi foonu ya oun lai gba ase, sugbon won ni adajo naa so pe koun to le da ejo naa, oun gbodo ri eri to daju pe looto ni.

Famous Edigbue to fesun kan Idris so pe esun ti won fi kan lodi si ofin, eyi lo see se ko da wahala sile laarin ilu.

Nibe ni Adajo Olajide Ilo to da ejo lojo naa ti so pe ese ti won ni Idris se ni idariji, eyi lo mu ki adajo naa so pe ki won gba beeli Idris ni egberun lona ogorun lojo naa, pelu oniduro, to si sun ejo naa si ojo keje osu keji odun yii.

Bo tile je pe iwa ti Idris hu lojo naa ku die kaato, sugbon gbogbo awon to gbo soro naa ni won bu enu ate lu igbese ti igbakeji gomina, Yetunde Onanuga gbe naa, won ni igbese naa ko bojumu to gege bi ipo to wa.

Won so pe gbogbo awon ti won n ba omo naa bebe lojo ni won le danu bi aja to ti ya digbolugi.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI