Ifowosowopo la nilo ni Yewa - Oba Olugbenle - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, January 19, 2017

Ifowosowopo la nilo ni Yewa - Oba Olugbenle

Oba Kehinde Gbadewole Olugbenle, Olu Ilaro ati Oba Alaye tile Yewa nipinle Ogun ti so pe awon ko nilo ohunkohun nile Yewa bi ko se pe kawon fowosowopo, nitori ohun nikan lo le je kawon rowo nibi idibo gomina ti yoo waye nipinle naa lodun 2019.

Oba Olugbenle soro yii lakoko to n ba oniroyin AWIKONKO soro fun ti idupe ayeye aadota odun to pe loke eepe, paapaa pelu bo tun se je pe ipo Oba Alaye lo wa lakoko naa. Kabiyesi so pe idunnu nla lo je foun lati wa niru ipo yii.

Fun awon to ba ni oye nipa ipo Gomina ipinle Ogun, yoo mo pe latodun 1976 ti won ti da ipinle naa sile, ko tii si gomina Kankan to ti je, to si je pe omo Yewa ni, awon eeyan lati Egba, Ijebu ati Remo nikan ni won n je gomina.

Lati nnkan bi odun mejila seyin lawon Yewa ti n dupo naa, sugbon isoro ti won ni ni bi ko se isokan laarin won, eyi lo si n je ki won ja kule lakoko idibo gomina niyen.

Oba Olugbenle, to tun je alaga awon Oba nipinle Ogun so pe idunnu nla ni yoo je foun nigba toun ba rii pe omo Yewa lo wole gege bi gomina lodun 2019.

Ninu oro e, o so pe “ Nnkan ti mo fe ni isokan ile Yewa. Mo fe ki ile Yewa tubo ni ifowosowopo ati isokan ju bayii lo, ki a le de ibi to ye ka de nipa idagbasoke. Ni gbogbo ona ni Olorun ti dara si wa. E yi ni a si le lo lati fi kun okun wa. O dami loju pe nigba ti m ba si wa laye, a maa jokoo lori aga to wa ni ofiisi gomina l’Oke-Mosan yen. Gbogbo nnkan to ye ka se la ti se nipa gbigbaruku ti awon ekun miran, o si dami loju pea won ekun toku naa maa fowosowopo pelu wa lati rowo mu.

“A le rii gba, nitori naa, a maa ri gba lakoko to ye. Opo awon omo wa lokunrin ati lobinrin la ni ti won kaju osuwon, pelu ipo ti won wa nibi ise ti won yan laayo. A o beere fun ipinle Yewa, sugbon ile gomina la n beere fun.”

Nigba to n soro lori bo se de ipo alaga awon Oba nipinle Ogun, Oba Olugbenle so pe ohun ko lobi fun ipo naa nitori pe, se ni ipo naa n yi kiri. O so pe asiko tipo naa yi ka noun ree, ohun ko bebe lati di alaga awon Oba alaye nipinle Ogun

Gege bi AWIKONKO se gbo, awon Oba alaye merin ni won n je alaga fawon Oba nipinle Ogun, awon naa ni; Alake tile Egba, Awujale tile Ijebu, Akarigbo tile Remo ati Olu Ilaro. Akarigbo lo sese kuro nibe ki Oba Olugbenle to bo sipo naa.

Bakanna la tun gbo pe lakoko ti Otunba Justus Olugbenga Daniel, OGD wa gege bi gomina ipinle Ogun ni won ti bere sii yan alaga fawon Oba nipinle Ogun, eyi to si n je kenu awon Oba nipinle naa maa ko, ki won maa fi ohun sokan laarin ara won.

Ninu oro Kabiyesi, o so pe “Ko si awuruju tabi ayadayida ninu bi mo se de ipo alaga fawon Oba. O foju han gbangba pee to ni. Inu mi dun lati so fun yin pe mo ti ko opolopo eko laarin awon Oba Alade. Awon alakoso awon Oba Alaye n beere fun eto won nitori ipo tawon to wa nibe wa. Sugbon mo dupe lowo Olorun pe mo n se ojuse mi bo ti to ati bo ti ye.”

Oba Alaye naa, to tun je okan lara awon oluso aguntan ninu ijo Irapada, Redeemed Christian Church of God so pe ko si isoro kankan foun lati maa sise meji papo, o so pe oun kii se onisegun, bee oun kii foribale fun orisa.

Oba Olugbenle so pe looto loun bowo fun asa ati ise pupo, sugbon iyen ko so pe koun sin Olorun oun, bee si ni ko so pe koun lo foribale fun orisa tabi lo rubo fawon orisa. Kabiyesi so pe, o lawon ti won wa nibe.

Alaga fawon Oba Alade naa tun so pe anfaani nla lo je foun lati wa nibi toun wa loni pelu ojo ori oun. O so pe aseyori nla ni. Oun si ti mu ayanmo oun se gege bi Olu Ilaro ati Oba Alaye Ile Yewa, o loun ko tun le beere ohunkohun mo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI