Bi idibo gomina nipinle Ogun ti se n
sunmo etile bayii, oro naa ti fi n han gbangba gbangba pe awon Ijebu ti n dana
sile bayii lati gbee koju awon Yewa nibi idibo gomina odun 2019 to n bo lona,
pelu bo se je pe orin tawon Yewa n ko bayii nip e “Yewa lo kan; Awa lo kan. Idibo gomina odun 2019, Yewa lo kan.”
Bee ni won lawon Ijebu naa ti n lu
ilu “Apepe” bayii pe, “Ao ni gba, awa la
ni; Aga gomina ipinle Ogun, Awa la ni”. Ti won si n rawo ebe sawon omo
ipinle Ogun pe ki won fowosowopo pelu awon lodun 2019.
Titi di akoko yi, ko sorin meji tawon
omo bibi Yewa n ko bayii, bi ko se orin “YAYI
la fe” lo, iyen Senato Adeola Olamilekan Solomon to n soju ekun kan nipinle
Ekoo nile igbimo asofin agba nilu Abuja. Bee lawon kan n bebe korin pe ki won
fun eni to ti pe nibi ere ije naa laye, iyen Gboyega Nasiru Isiaka, GNI, eni to
ti tiraka lati du ipo naa leemeji.
Bee lawon Ijebu naa o leni meji
ti won fee fun laye bi ko se Onarebu Ladi Adebutu Keshinton, topo mo si LADO,
eni to je okan lara awon omo ogbontarigi onisowo nni, Adebutu Keshinton, topo
mo on si Baba Ijebu.
Sibe, a o gbodo foju fo okan lara
awon awon agba oselu nni, toun naa tiraka se ipo keta nibi idibo gomina nipinle
naa, Otunba Olatunde Olarotimi Paseda, eni toun naa ti n so pe, oun ko nii gba
lodun 2019 naa.
Ohun to tun n je kayeefi ni bayii
ni bi Gomina Ibikunle Amosun se ti n so pe, ko seni ti yoo gba aga naa nidi oun
ninu awon to n leri yi naa. Amosun so pe oun nikan loun mo eni ti yoo gba aga
naa lodun 2019.
Sugbon ohun to tun n je iyalenu
ni tawon agba oselu meta nni, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, Oloye Olusegun Osoba
ati Otunba Gbenga Daniel ko se fi ara won sere lasiko yii, to je pe tosan toru
ni won fi n se ipade bonkele lati je ki ipinu won wa si imuse.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO
lowo, won ni ipade tawon agba oselu naa n se ni bi won ko se ni fun Gomina
Amosun laaye lati fa eeyan kale gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019, iyen eni
to n so pe yoo gba ipo naa lowo oun.
No comments:
Post a Comment