Sefiu Alao |
AWIKONKO gbo pe latigba tisele buruku kan ti sele nibi ti ilu mooka
olorin Fuji na ti n rin tifura-tifura bo tile je pe kp baayan kan kan ni
gbolohun aso, tabi pe oun atenikan jo n leri iku sira won.
Laipe yi ni agba onkorin naa, Sefiu Alao, to je oludasile Fuji Cadozo lo
sere fawon ololufee e nibi ayeye kan nilu Sagamu, nibi ti won so pe ori ti ko
Sefiu yo lowo asita ibon kan to deede jabo lowo osise alaabo kan ti won gba
sibe.
Ohun taa gbo ni pe obinrin kan to n na owo lowo fun Sefiu Alao loju agbo
lo se sababi asita ibon naa to so gba be ku lakoko ti won n gbe lo si osibitu
kan to sunmo.
Bo tile je pe orisirisi la gbo nipa isele naa, ti a ko tii fidi oro naa
mule lati ba Sefiu, Baba Rafia soro funra e. Ko tii gba oniroyin kankan laye
lati beere boro naa se je, sugbon orisirisi lawon to sunmo Sefiu naa n so, okan
o jora won loro ti won n so.
Bawon kan se n so pe awon agbanipa ni won ran si Sefiu Alao lojo naa,
bee lawon kan n so pe asita ibon ni, awon mi in tun n so pe won fee dan Sefiu
wo ni boya o duro giri, sugbon awa ko le so nitori a ko si nibe.
AWIKONKO tun gbo pe lakoko ti eso alaabo naa n tun ibon e se ni o see si
yinbon naa to si wole sara obinrin to wa niwaju Sefiu gba odikeji jade sita.
Won ni nnkan to da pati ru lojo naa niyen nitori se ni won ro pe awon
odo alagidi ti won feran lati maa da pati ru tun ti bere ni, eyi to fa ti
gbogbo awon to wa nibe fi na papa bora.
Awon kan so pe latigba naa ni won ti gba Sefiu lamoran pe ko ye
maa darin mo lai lo awon godogodo eso alaabo lati maa daabo bo emi e, nitori
won so pe eleeketa tiru isele yi maa waye niyi.
No comments:
Post a Comment